Ìfihàn 15 BM

Àwọn Angẹli tí Ó Mú Àjàkálẹ̀ Àrùn Ìkẹyìn Wá

1 Mo tún rí ohun abàmì mìíràn ní ọ̀run, ohun ńlá ati ohun ìyanu: àwọn angẹli meje tí àjàkálẹ̀ àrùn meje ti ìkẹyìn wà ní ìkáwọ́ wọn, nítorí pé àwọn ni wọ́n mú ibinu Ọlọrun wá sí òpin.

2 Mo tún rí ohun tí ó dàbí òkun dígí tí iná wà ninu rẹ̀. Àwọn kan dúró lẹ́bàá òkun dígí náà, àwọn tí wọ́n ti ṣẹgun ẹranko náà ati ère rẹ̀, ati iye orúkọ rẹ̀. Wọ́n mú hapu Ọlọrun lọ́wọ́,

3 wọ́n ń kọ orin Mose iranṣẹ Ọlọrun ati orin Ọ̀dọ́ Aguntan náà pé,“Iṣẹ́ ńlá ati iṣẹ́ ìyanu ni iṣẹ́ rẹ,Oluwa, Ọlọrun Olodumare.Òdodo ati òtítọ́ ni àwọn iṣẹ́ ọnà rẹ,Ọba àwọn orílẹ̀-èdè.

4 Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ, Oluwa?Ta ni kò ní fi ògo fún orúkọ rẹ?Nítorí ìwọ nìkan ni ó pé,nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá,wọn yóo júbà níwájú rẹ,nítorí òdodo rẹ farahàn gbangba.”

5 Lẹ́yìn èyí mo tún rí Tẹmpili tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run. Àgọ́-Ẹ̀rí wà ninu rẹ̀.

6 Àwọn angẹli meje tí wọ́n ní àjàkálẹ̀ àrùn meje níkàáwọ́ jáde láti inú Tẹmpili náà wá, wọ́n wọ aṣọ funfun tí ó ń tàn bí ìmọ́lẹ̀. Wúrà ni wọ́n fi ṣe ìgbàyà wọn.

7 Ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè náà fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje náà ní àwo wúrà kéékèèké kọ̀ọ̀kan, àwọn àwo wúrà yìí kún fún ibinu Ọlọrun, ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae.

8 Inú Tẹmpili wá kún fún èéfín ògo Ọlọrun ati ti agbára rẹ̀. Kò sí ẹni tí ó lè wọ inú Tẹmpili títí tí àwọn àjàkálẹ̀ àrùn meje ti àwọn angẹli meje náà fi parí.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22