Ìfihàn 4 BM

Ìsìn ní Ọ̀run

1 Lẹ́yìn èyí mo tún rí ìran mìíran. Mo rí ìlẹ̀kùn kan tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run. Mo wá gbọ́ ohùn kan bíi ti àkọ́kọ́.Tí ó dàbí ìgbà tí kàkàkí bá ń dún, tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀. Ó ní, “Gòkè wá níhìn-ín. N óo fi àwọn ohun tí ó níláti ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí hàn ọ́.”

2 Lẹsẹkẹsẹ ni Ẹ̀mí bá gbé mi. Mo bá rí ìtẹ́ kan ní ọ̀run. Ẹnìkan jókòó lórí rẹ̀.

3 Ojú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà dàbí òkúta iyebíye oríṣìí meji. Òṣùmàrè yí ìtẹ́ náà ká, ó ń tan ìmọ́lẹ̀ bí òkúta iyebíye.

4 Àwọn ìtẹ́ mẹrinlelogun ni wọ́n yí ìtẹ́ náà ká. Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun sì jókòó lórí ìtẹ́ mẹrinlelogun náà. Wọ́n wọ aṣọ funfun, wọ́n dé adé wúrà.

5 Mànàmáná ati ìró ààrá ń jáde láti ara ìtẹ́ tí ó wà láàrin. Ògùṣọ̀ meje tí iná wọn ń jó wà níwájú ìtẹ́ náà. Àwọn yìí ni Ẹ̀mí Ọlọrun meje.

6 Iwájú ìtẹ́ náà dàbí òkun dígí, ó rí bíi yìnyín, ó mọ́ gaara.Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin kan wà ní ààrin, wọ́n yí ìtẹ́ náà ká. Wọ́n ní ọpọlọpọ ojú níwájú ati lẹ́yìn.

7 Ekinni dàbí kinniun, ekeji dàbí akọ mààlúù, ojú ẹkẹta jọ ti eniyan, ẹkẹrin sì dàbí idì tí ó ń fò.

8 Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà ní apá mẹfa. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ọpọlọpọ ojú. Wọn kì í sinmi tọ̀sán-tòru, wọ́n ń wí pé,“Mímọ́! Mímọ́! Mímọ́!Oluwa Ọlọrun Olodumare.Ẹni tí ó ti wà, tí ó wà nisinsinyii,tí ó sì ń bọ̀ wá.”

9 Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá fi ògo, ọlá ati ìyìn fún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae,

10 àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà á dojúbolẹ̀ níwájú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wọn a júbà ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae, wọn a fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n a máa wí pé,

11 “Oluwa Ọlọrun wa, ìwọ ni ó tọ́ sí láti gba ògo, ati ọlá ati agbára.Nítorí ìwọ ni ó dá ohun gbogbo,ati pé nípa ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà,nípa rẹ ni a sì ṣe dá wọn.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22