Ìfihàn 2 BM

Iṣẹ́ sí Ìjọ Efesu

1 “Kọ ìwé yìí sí òjíṣẹ́ ìjọ Efesu:“Ẹni tí ó di ìràwọ̀ meje mú ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, tí ó ń rìn láàrin àwọn ọ̀pá fìtílà wúrà meje wí báyìí pé,

2 Mo mọ iṣẹ́ rẹ, ati làálàá rẹ, ati ìfaradà rẹ. Mo mọ̀ pé o kò jẹ́ gba àwọn eniyan burúkú mọ́ra. O ti dán àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọn kì í ṣe aposteli wò, o ti rí i pé òpùrọ́ ni wọ́n.

3 O ní ìfaradà. O ti farada ìyà nítorí orúkọ mi, o kò sì jẹ́ kí àárẹ̀ mú ọ.

4 Ṣugbọn mo ní nǹkan wí sí ọ. O ti kọ ìfẹ́ tí o ní nígbà tí o kọ́kọ́ gbàgbọ́ sílẹ̀.

5 Nítorí náà, ranti bí o ti ga tó tẹ́lẹ̀ kí o tó ṣubú; ronupiwada, kí o sì ṣiṣẹ́ bíi ti àkọ́kọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, mò ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, bí o kò bá ronupiwada, n óo mú ọ̀pá fìtílà rẹ kúrò ní ipò rẹ̀.

6 Ṣugbọn ò ń ṣe kinní kan tí ó dára: o kórìíra iṣẹ́ àwọn Nikolaiti, tí èmi náà kórìíra.

7 “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.“Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo fún ní àṣẹ láti jẹ ninu èso igi ìyè tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun.

Iṣẹ́ sí Ìjọ Simana

8 “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Simana:“Báyìí ni ẹni kinni ati ẹni ìkẹyìn wí, ẹni tí ó kú, tí ó tún wà láàyè:

9 Mo mọ̀ pé o ní ìṣòro; ati pé o ṣe aláìní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́rọ̀ ni ọ́ ní ọ̀nà mìíràn. Mo mọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tí àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní Juu ń sọ, àwọn tí kì í sì í ṣe Juu; tí ó jẹ́ pé ilé ìpàdé Satani ni wọ́n.

10 Má bẹ̀rù ohunkohun tí ò ń bọ̀ wá jìyà. Èṣù yóo gbé ẹlòmíràn ninu yín jù sinu ẹ̀wọ̀n láti fi dán yín wò. Fún ọjọ́ mẹ́wàá ẹ óo ní ìṣòro pupọ. Ṣugbọn jẹ́ olóòótọ́ dé ojú ikú, Èmi yóo sì fún ọ ní adé ìyè.

11 “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.“Ẹni tí ó bá ṣẹgun kò ní kú ikú keji.

Iṣẹ́ sí Ìjọ Pẹgamu

12 “Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Pẹgamu pé:“Ẹni tí ó ní idà olójú meji tí ó mú ní:

13 Mo mọ ibi tí ò ń gbé, ibẹ̀ ni Satani tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí. Sibẹ o di orúkọ mi mú, o kò bọ́hùn ninu igbagbọ ní ọjọ́ tí wọ́n pa Antipasi ẹlẹ́rìí òtítọ́ mi ní ìlú yín níbi tí Satani fi ṣe ilé.

14 Ṣugbọn mo ní àwọn nǹkan díẹ̀ wí sí ọ. O ní àwọn kan láàrin ìjọ tí wọ́n gba ẹ̀kọ́ Balaamu, ẹni tí ó kọ́ Balaki láti fi ohun ìkọsẹ̀ siwaju àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n fi ń jẹ oúnjẹ ìbọ̀rìṣà, tí wọ́n tún ń ṣe àgbèrè.

15 O tún ní àwọn kan tí àwọn náà gba ẹ̀kọ́ àwọn Nikolaiti.

16 Nítorí náà, ronupiwada. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ n óo wá láìpẹ́, n óo sì fi idà tí ó wà lẹ́nu mi bá wọn jà.

17 “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.“Ẹni tí ó bá ṣẹgun, Èmi óo fún un ní mana tí a ti fi pamọ́. N óo tún fún un ní òkúta funfun kan tí a ti kọ orúkọ titun sí lára. Ẹnikẹ́ni kò mọ orúkọ titun yìí àfi ẹni tí ó bá gba òkúta náà.

Iṣẹ́ sí Ìjọ Tiatira

18 “Kọ ìwé yìí sí ìjọ Tiatira pé:“Ọmọ Ọlọrun, ẹni tí ojú rẹ̀ dàbí ọwọ́ iná, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ń dán bí idẹ.

19 Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Mo mọ ìfẹ́ rẹ ati igbagbọ rẹ, mo mọ iṣẹ́ rere tí ò ń ṣe ati ìfaradà rẹ. Iṣẹ́ rẹ ti ìkẹyìn tilẹ̀ dára ju ti àkọ́kọ́ lọ.

20 Ṣugbọn mo ní nǹkan wí sí ọ. O gba obinrin tí wọn ń pè ní Jesebẹli láàyè. Ó ń pe ara rẹ̀ ní aríran, ó ń tan àwọn iranṣẹ mi jẹ, ó ń kọ́ wọn láti ṣe àgbèrè ati láti jẹ oúnjẹ ìbọ̀rìṣà.

21 Mo fún un ní àkókò kí ó ronupiwada, ṣugbọn kò fẹ́ ronupiwada kúrò ninu ìwà àgbèrè rẹ̀.

22 N óo dá a dùbúlẹ̀ àìsàn. Ìṣòro pupọ ni yóo bá àwọn tí wọ́n bá bá a ṣe àgbèrè, àfi bí wọ́n bá rí i pé iṣẹ́ burúkú ni ó ń ṣe, tí wọn kò sì bá a lọ́wọ́ ninu rẹ̀ mọ́.

23 N óo fi ikú pa àwọn ọmọ rẹ̀. Gbogbo àwọn ìjọ ni yóo wá mọ̀ pé Èmi ni Èmi máa ń wádìí ọkàn ati èrò ẹ̀dá, n óo sì fi èrè fún olukuluku yín gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

24 “Ṣugbọn ẹ̀yin yòókù ní Tiatira, ẹ̀yin tí ẹ kò gba ẹ̀kọ́ obinrin yìí, ẹ̀yin tí ẹ kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí wọn ń pè ní ohun ìjìnlẹ̀ Satani, n kò ní di ẹrù mìíràn rù yín mọ́.

25 Ṣugbọn ṣá, ẹ di ohun tí ẹ ní mú ṣinṣin títí n óo fi dé.

26-28 Ẹni tí ó bá ṣẹgun, tí ó forí tì í, tí ó ń ṣe iṣẹ́ mi títí dé òpin, òun ni n óo fún ní àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè, ọ̀pá irin ni yóo fi jọba lórí wọn, bí ìkòkò amọ̀ ni yóo fọ́ wọn túútúú. Irú àṣẹ tí mo gbà lọ́dọ̀ Baba mi ni n óo fún un. N óo tún fún un ní ìràwọ̀ òwúrọ̀.

29 “Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22