Ìfihàn 10 BM

Angẹli ati Ìwé-kíká Kékeré

1 Mo tún rí angẹli alágbára mìíràn, tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá. Ó fi ìkùukùu bora, òṣùmàrè sì yí orí rẹ̀ ká; ojú rẹ̀ dàbí oòrùn; ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí òpó iná.

2 Ó mú ìwé kékeré kan lọ́wọ́ tí ó wà ní ṣíṣí. Ó gbé ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ lé orí òkun, ó sì gbé ti òsì lé orí ilẹ̀ ayé.

3 Ó wá bú ramúramù bíi kinniun. Nígbà tí ó bú báyìí tán, ààrá meje sán.

4 Nígbà tí ààrá meje yìí ń sán, mo fẹ́ máa kọ ohun tí wọn ń sọ sílẹ̀, ṣugbọn mo gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run, tí ó sọ pé, “Àṣírí ni ohun tí àwọn ààrá meje yìí ń sọ, má kọ wọ́n sílẹ̀.”

5 Angẹli náà tí mo rí, tí ó gbé ẹsẹ̀ lé orí òkun, ati orí ilẹ̀, wá gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sí òkè ọ̀run,

6 ó fi ẹni tí ó wà láàyè lae ati títí laelae búra, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ohun tí ó wà ninu rẹ̀, tí ó dá ayé ati ohun tí ó wà ninu rẹ̀, tí ó dá òkun ati ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Ó ní kò sí ìjáfara mọ́.

7 Ní ọjọ́ tí angẹli keje bá fọhùn, nígbà tí ó bá fẹ́ fun kàkàkí tirẹ̀, àṣírí ète Ọlọrun yóo ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀.

8 Mo tún gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run tí ó sọ fún mi pé, “Lọ gba ìwé tí ó wà ni ṣíṣí tí ó wà lọ́wọ́ angẹli tí ó dúró lórí òkun ati lórí ilẹ̀.”

9 Mo bá lọ sọ́dọ̀ angẹli náà, mo ní kí ó fún mi ní ìwé kékeré náà. Ó ní, “Gbà, kí o jẹ ẹ́. Yóo dùn ní ẹnu rẹ bí oyin, ṣugbọn yóo korò ní ikùn rẹ.”

10 Mo bá gba ìwé náà ní ọwọ́ angẹli yìí, mo bá jẹ ẹ́. Ó dùn bí oyin ní ẹnu mi. Ṣugbọn nígbà tí mo gbé e mì, ó korò ní ikùn mi.

11 Wọ́n bá sọ fún mi pé, “O níláti tún kéde fún ọ̀pọ̀ àwọn eniyan ati oríṣìíríṣìí ẹ̀yà ati àwọn orílẹ̀-èdè, ati ọpọlọpọ ìjọba.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22