Ìfihàn 14 BM

Orin Àwọn Ọ̀kẹ́ Meje Ó Lé Ẹgbaaji (144,000) Eniyan

1 Mo rí Ọ̀dọ́ Aguntan náà tí ó dúró lórí òkè Sioni, pẹlu àwọn ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹgbaaji (144,000) eniyan tí a kọ orúkọ rẹ̀ ati orúkọ Baba rẹ̀ sí wọn níwájú.

2 Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run bí ìró ọpọlọpọ omi ati bí ìgbà tí ààrá líle bá ń sán. Ohùn tí mo gbọ́ ni ti àwọn oníhapu tí wọn ń lu hapu wọn.

3 Wọ́n ń kọrin titun kan níwájú ìtẹ́ náà ati níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun. Kò sí ẹni tí ó lè mọ orin náà àfi àwọn ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹgbaaji (144,000) eniyan tí a ti rà pada ninu ayé.

4 Àwọn ni àwọn tí kò fi obinrin ba ara wọn jẹ́, nítorí wọn kò bá obinrin lòpọ̀ rí. Àwọn yìí ni wọ́n ń tẹ̀lé Ọ̀dọ́ Aguntan náà káàkiri ibi gbogbo tí ó bá ń lọ. Àwọn ni a ti rà pada láti inú ayé, wọ́n dàbí èso àkọ́so fún Ọlọrun ati fún Ọ̀dọ́ Aguntan.

5 Ọ̀rọ̀ èké kankan kò sí ní ẹnu wọn. Kò sí àléébù ninu ìgbé-ayé wọn.

Iṣẹ́ tí Àwọn Angẹli Mẹta Jẹ́

6 Mo tún rí angẹli mìíràn tí ń fò lágbedeméjì ọ̀run. Ó mú ìyìn rere ayérayé lọ́wọ́ láti kéde rẹ̀ fún àwọn tí wọ́n wà ninu ayé, ninu gbogbo ẹ̀yà ati gbogbo orílẹ̀-èdè.

7 Ó bá kígbe pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọrun kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí àkókò ìdájọ́ rẹ̀ dé! Ẹ júbà ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, òkun ati gbogbo orísun omi.”

8 Angẹli mìíràn tẹ̀lé ti àkọ́kọ́, ó ní, “Ó ti tú! Babiloni ìlú ńlá nnì ti tú! Ìlú tí ó fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní ọtí àgbèrè rẹ̀ mu, tí ó mú ibinu Ọlọrun wá, ó ti tú!”

9 Angẹli kẹta wá tẹ̀lé wọn. Ó kígbe pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá júbà ẹranko náà ati ère rẹ̀, tí ó gba àmì rẹ̀ siwaju rẹ̀ tabi sí ọwọ́ rẹ̀,

10 yóo mu ninu ògidì ọtí ibinu Ọlọrun, tí ó wà ninu ife ibinu rẹ̀. Olúwarẹ̀ yóo joró ninu iná àjóòkú níwájú àwọn angẹli mímọ́ ati Ọ̀dọ́ Aguntan.

11 Èéfín iná oró àwọn tí wọ́n bá júbà ẹranko náà ati ère rẹ̀, tí wọ́n gba àmì orúkọ rẹ̀, yóo máa rú títí lae. Kò ní rọlẹ̀ tọ̀sán-tòru.”

12 Èyí mú kí ó di dandan fún àwọn eniyan Ọlọrun, tí wọn ń pa àṣẹ Ọlọrun mọ́, tí wọ́n sì dúró ninu igbagbọ Jesu láti ní ìfaradà.

13 Mo gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá tí ó sọ pé, “Kọ ọ́ sílẹ̀! Àwọn òkú tí wọ́n kú ninu Oluwa láti àkókò yìí lọ ṣe oríire.”Ẹ̀mí jẹ́rìí sí i pé, “Bẹ́ẹ̀ ni dájúdájú, nítorí wọn yóo sinmi ninu làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn yóo máa tọ̀ wọ́n lẹ́yìn.”

Ìkórè Ayé

14 Mo wá rí ìkùukùu funfun. Ẹnìkan tí ó dàbí ọmọ eniyan jókòó lórí ìkùukùu náà. Ó dé adé wúrà. Ó mú dòjé tí ó mú lọ́wọ́.

15 Angẹli mìíràn jáde láti inú Tẹmpili wá, ó kígbe sí ẹni tí ó jókòó lórí ìkùukùu, pé, “Iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ fún dòjé rẹ; àkókò ìkórè tó: ilé ayé ti tó kórè.”

16 Ẹni tí ó jókòó lórí ìkùukùu náà bá ti dòjé rẹ̀ bọ ilé ayé, ni ó bá kórè ayé.

17 Angẹli mìíràn tún jáde wá láti inú Tẹmpili ní ọ̀run, tí òun náà tún mú dòjé mímú lọ́wọ́.

18 Angẹli mìíràn wá ti ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ ìrúbọ wá, òun ni ó ní àṣẹ lórí iná. Ó kígbe sí angẹli tí ó ní dòjé mímú pé, “Iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ fún dòjé mímú rẹ. Kó èso àwọn igi eléso ilé ayé jọ, nítorí pé wọ́n ti pọ́n.”

19 Ni angẹli tí ó ní dòjé náà bá ti dòjé rẹ̀ bọ inú ilé ayé, ó bá kó èso àjàrà ayé jọ, ó dà wọ́n sí ibi ìfúntí ibinu ńlá Ọlọrun.

20 Lẹ́yìn odi ìlú ni ìfúntí náà wà. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹ èso ninu rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí yọ jáde láti inú ìfúntí náà. Jíjìn rẹ̀ mu ẹṣin dé ọrùn, ó sì gba ilẹ̀ lọ ní nǹkan bí igba ibùsọ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22