5 A fún un ní ẹnu láti fi sọ̀rọ̀ tí ó ju ẹnu rẹ̀ lọ, ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. A fún un ní àṣẹ fún oṣù mejilelogoji.
6 Ó bá ya ẹnu, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ó ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí orúkọ Ọlọrun ati sí àgọ́ rẹ̀, ati sí àwọn tí wọ́n ń gbé ọ̀run.
7 A fún un ní agbára láti gbógun ti àwọn eniyan Ọlọrun ati láti ṣẹgun wọn. A tún fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ẹ̀yà ati orílẹ̀-èdè ati oríṣìíríṣìí èdè ati gbogbo eniyan.
8 Gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú ayé tí a kò kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè bá ń júbà rẹ̀. Láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé ni a kò ti kọ orúkọ wọn sinu ìwé Ọ̀dọ́ Aguntan tí a pa.
9 Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́!
10 Bí ẹnikẹ́ni bá níláti lọ sí ìgbèkùn, yóo lọ sí ìgbèkùn. Bí ẹnikẹ́ni bá fi idà pa eniyan, idà ni a óo fi pa òun náà. Níhìn-ín ni ìfaradà ati ìdúró ṣinṣin àwọn eniyan Ọlọrun yóo ti hàn.
11 Mo tún rí ẹranko mìíràn tí ó jáde láti inú ilẹ̀. Ó ní ìwo meji bíi ti Ọ̀dọ́ Aguntan. Ó ń sọ̀rọ̀ bíi ti Ẹranko Ewèlè.