1 Mo rí Ọ̀dọ́ Aguntan náà tí ó dúró lórí òkè Sioni, pẹlu àwọn ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹgbaaji (144,000) eniyan tí a kọ orúkọ rẹ̀ ati orúkọ Baba rẹ̀ sí wọn níwájú.
2 Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run bí ìró ọpọlọpọ omi ati bí ìgbà tí ààrá líle bá ń sán. Ohùn tí mo gbọ́ ni ti àwọn oníhapu tí wọn ń lu hapu wọn.
3 Wọ́n ń kọrin titun kan níwájú ìtẹ́ náà ati níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun. Kò sí ẹni tí ó lè mọ orin náà àfi àwọn ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹgbaaji (144,000) eniyan tí a ti rà pada ninu ayé.
4 Àwọn ni àwọn tí kò fi obinrin ba ara wọn jẹ́, nítorí wọn kò bá obinrin lòpọ̀ rí. Àwọn yìí ni wọ́n ń tẹ̀lé Ọ̀dọ́ Aguntan náà káàkiri ibi gbogbo tí ó bá ń lọ. Àwọn ni a ti rà pada láti inú ayé, wọ́n dàbí èso àkọ́so fún Ọlọrun ati fún Ọ̀dọ́ Aguntan.