1 Lẹ́yìn èyí mo tún rí angẹli tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ bọ̀. Ó ní àṣẹ ńlá. Gbogbo ayé mọ́lẹ̀ nítorí ẹwà ògo rẹ̀.
2 Ó wá kígbe pé, “Ó tú! Babiloni ìlú ńlá tú! Ó wá di ibi tí àwọn àǹjọ̀nnú ń gbé, tí ẹ̀mí Èṣù oríṣìíríṣìí ń pààrà, tí oríṣìíríṣìí ẹyẹkẹ́yẹ ń kiri.
3 Nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ti mu àmuyó ninu ọtí àgbèrè rẹ̀, ọtí tí ó fa ibinu Ọlọrun. Àwọn ọba ilẹ̀ ayé ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀, àwọn oníṣòwò ilẹ̀ ayé ti di olówó nípa ìwà jayéjayé rẹ̀.”
4 Mo tún gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run tí ó sọ pé,“Ẹ jáde kúrò ninu rẹ̀, ẹ̀yin eniyan mi,kí ẹ má baà ní ìpín ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,kí ẹ má baà fara gbá ninu ìjìyà rẹ̀.
5 Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga dé ọ̀run,Ọlọrun kò gbàgbé àìṣedéédé rẹ̀.