2 Ó wá kígbe pé, “Ó tú! Babiloni ìlú ńlá tú! Ó wá di ibi tí àwọn àǹjọ̀nnú ń gbé, tí ẹ̀mí Èṣù oríṣìíríṣìí ń pààrà, tí oríṣìíríṣìí ẹyẹkẹ́yẹ ń kiri.
3 Nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ti mu àmuyó ninu ọtí àgbèrè rẹ̀, ọtí tí ó fa ibinu Ọlọrun. Àwọn ọba ilẹ̀ ayé ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀, àwọn oníṣòwò ilẹ̀ ayé ti di olówó nípa ìwà jayéjayé rẹ̀.”
4 Mo tún gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run tí ó sọ pé,“Ẹ jáde kúrò ninu rẹ̀, ẹ̀yin eniyan mi,kí ẹ má baà ní ìpín ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,kí ẹ má baà fara gbá ninu ìjìyà rẹ̀.
5 Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga dé ọ̀run,Ọlọrun kò gbàgbé àìṣedéédé rẹ̀.
6 Ṣe fún un bí òun náà ti ṣe fún eniyan.Gbẹ̀san lára rẹ̀ ní ìlọ́po meji ìwà rẹ̀.Ife tí ó fi ń bu ọtí fún eniyan nikí o fi bu ọtí tí ó le ní ìlọ́po meji fún òun alára.
7 Bí ó ti ṣe ń jẹ ọlá,tí ó ń jẹ ayé tẹ́lẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kí o fún un ní ìrora ati ìbànújẹ́.Ó ń sọ ní ọkàn rẹ̀ pé,‘Ọba orí ìtẹ́ ni mí,èmi kì í ṣe opó,ojú mi kò ní rí ìbànújẹ́.’
8 Nítorí èyí, ní ọjọ́ kan náà ni oríṣìíríṣìí òfò yóo dé bá a,ati àjàkálẹ̀ àrùn, ati ọ̀fọ̀, ati ìyàn.Iná yóo tún jó o ní àjórun,nítorí alágbára ni Oluwa Ọlọrun tí ó ti ń ṣe ìdájọ́ fún un.”