7 Ọ̀dọ́ Aguntan náà bá wá, ó sì gba ìwé náà ní ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́.
8 Nígbà tí ó gbà á, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn mẹrinlelogun náà dojúbolẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Aguntan yìí. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn mú hapu kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́, ati àwo wúrà kéékèèké, tí ó kún fún turari. Turari yìí ni adura àwọn eniyan Ọlọrun, àwọn onigbagbọ.
9 Wọ́n wá ń kọ orin titun kan, pé,“Ìwọ ni ó tọ́ sí láti gba ìwé náà,ati láti tú èdìdì ara rẹ̀.Nítorí wọ́n pa ọ́,o sì ti fi ẹ̀jẹ̀ rẹ bá Ọlọrun ṣe ìràpadà eniyan,láti inú gbogbo ẹ̀yà,ati gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè.
10 O ti sọ wọ́n di ìjọba ti alufaa láti máa sin Ọlọrun wa.Wọn yóo máa jọba ní ayé.”
11 Bí mo tí ń wò, mo gbọ́ ohùn ọpọlọpọ àwọn angẹli tí wọ́n yí ìtẹ́ náà ká ati àwọn ẹ̀dá alààyè ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun. Àwọn angẹli náà pọ̀ pupọ: ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹrun àìmọye.
12 Wọ́n ń kígbe pé,“Ọ̀dọ́ Aguntan tí a ti pa ni ó tọ́ síláti gba agbára, ọrọ̀, ọgbọ́n, ipá, ọlá, ògo ati ìyìn.”
13 Mo bá tún gbọ́ tí gbogbo ẹ̀dá tí ó wà lọ́run ati ní orílẹ̀ ayé, ati nísàlẹ̀ ilẹ̀, ati lórí òkun, ati ohun gbogbo tí ń bẹ ninu òkun, ń wí pé,“Ìyìn, ọlá, ògo, ati agbára ni ti ẹnití ó jókòó lórí ìtẹ́ ati Ọ̀dọ́ Aguntan lae ati laelae.”