1 Ṣé a óo ṣẹ̀ṣẹ̀ tún bẹ̀rẹ̀ láti máa ṣe àpèjúwe ara wa ni; àbí a nílò láti mú ìwé ẹ̀rí tọ̀ yín wá tí yóo sọ irú ẹni tí a jẹ́ fun yín, tabi kí á gbà lọ láti ọ̀dọ̀ yín?
2 Ẹ̀yin alára ni ìwé wa, tí a ti kọ sí ọkàn wa. Gbogbo eniyan ni wọ́n mọ ìwé yìí, tí wọ́n sì ń kà á.
3 Ó hàn gbangba pé ẹ̀yin ni ìwé tí Kristi kọ, tí ó fi rán wa. Kì í ṣe irú èyí tí wọ́n fi yíǹkì kọ, Ẹ̀mí Ọlọrun alààyè ni wọ́n fi kọ ọ́. Kì í ṣe èyí tí wọ́n kọ sí orí òkúta; ọkàn eniyan ni wọ́n kọ ọ́ sí.
4 A lè sọ èyí nítorí a ní igbẹkẹle ninu Ọlọrun nípa Kristi.