16 Awọn ọmọ Keni, ana Mose, si bá awọn ọmọ Juda gòke lati ilu ọpẹ lọ si aginjù Juda, ni gusù Aradi; nwọn si lọ, nwọn si mbá awọn enia na gbé.
17 Juda si bá Simeoni arakunrin rẹ̀ lọ, nwọn si pa awọn ara Kenaani ti ngbé Sefati, nwọn si pa a run patapata. A si pè orukọ ilu na ni Horma.
18 Juda si kó Gasa pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Aṣkeloni pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Ekroni pẹlu àgbegbe rẹ̀.
19 OLUWA si wà pẹlu Juda; o si gbà ilẹ òke; nitori on kò le lé awọn enia ti o wà ni pẹtẹlẹ̀ jade, nitoriti nwọn ní kẹkẹ́ irin.
20 Nwọn si fi Hebroni fun Kalebu, gẹgẹ bi Mose ti wi: on si lé awọn ọmọ Anaki mẹtẹta jade kuro nibẹ̀.
21 Awọn ọmọ Benjamini kò si lé awọn Jebusi ti ngbé Jerusalemu jade; ṣugbọn awọn Jebusi mbá awọn ọmọ Benjamini gbé ni Jerusalemu titi di oni.
22 Ati awọn ara ile Josefu, awọn pẹlu si gòke lọ bá Beti-eli jà: OLUWA si wà pẹlu wọn.