18 Juda si kó Gasa pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Aṣkeloni pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Ekroni pẹlu àgbegbe rẹ̀.
19 OLUWA si wà pẹlu Juda; o si gbà ilẹ òke; nitori on kò le lé awọn enia ti o wà ni pẹtẹlẹ̀ jade, nitoriti nwọn ní kẹkẹ́ irin.
20 Nwọn si fi Hebroni fun Kalebu, gẹgẹ bi Mose ti wi: on si lé awọn ọmọ Anaki mẹtẹta jade kuro nibẹ̀.
21 Awọn ọmọ Benjamini kò si lé awọn Jebusi ti ngbé Jerusalemu jade; ṣugbọn awọn Jebusi mbá awọn ọmọ Benjamini gbé ni Jerusalemu titi di oni.
22 Ati awọn ara ile Josefu, awọn pẹlu si gòke lọ bá Beti-eli jà: OLUWA si wà pẹlu wọn.
23 Awọn ara ile Josefu rán amí lọ si Beti-eli. (Orukọ ilu na ni ìgba atijọ rí si ni Lusi.)
24 Awọn amí na si ri ọkunrin kan ti o ti inu ilu na jade wá, nwọn si wi fun u pe, Awa bẹ̀ ọ, fi ọ̀na atiwọ̀ ilu yi hàn wa, awa o si ṣãnu fun ọ.