4 Samsoni si lọ o mú ọdunrun kọ̀lọkọlọ, o si mú ètufu, o si fi ìru wọn kò ìru, o si fi ètufu kan sãrin ìru meji.
5 Nigbati o si ti fi iná si ètufu na, o jọwọ wọn lọ sinu oko-ọkà awọn Filistini, o si kun ati eyiti a dì ni ití, ati eyiti o wà li oró, ati ọgbà-olifi pẹlu.
6 Nigbana li awọn Filistini wipe, Tani ṣe eyi? Nwọn si dahùn pe, Samsoni, ana ara Timna ni, nitoriti o gbà obinrin rẹ̀, o si fi i fun ẹgbẹ rẹ̀. Awọn Filistini si gòke wá, nwọn si fi iná sun obinrin na ati baba rẹ̀.
7 Samsoni si wi fun wọn pe, Bi ẹnyin ba ṣe irú eyi, dajudaju emi o gbẹsan lara nyin, lẹhin na emi o si dẹkun.
8 On si kọlù wọn, o si pa wọn ni ipakupa: o si sọkalẹ o si joko ni pàlàpálá apata Etamu.
9 Nigbana li awọn Filistini gòke lọ, nwọn si dótì Juda, nwọn si tẹ́ ara wọn lọ bẹrẹ ni Lehi.
10 Awọn ọkunrin Juda si wipe, Nitori kili ẹnyin ṣe gòke tọ̀ wa wá? Nwọn si dahùn wipe, Lati dè Samsoni li awa ṣe wá, lati ṣe si i gẹgẹ bi on ti ṣe si wa.