3 On si kó ẹdẹgbẹfa owo fadakà na fun iya rẹ̀ pada, iya rẹ̀ si wipe, Patapata ni mo yà fadakà wọnni sọ̀tọ fun OLUWA kuro li ọwọ́ mi, fun ọmọ mi, lati fi ṣe ere fifin ati ere didà: njẹ nitorina emi o fun ọ pada.
4 Ṣugbọn o kó owo na pada fun iya rẹ̀; iya rẹ̀ si mú igba owo fadakà, o si fi i fun oniṣọnà, ẹniti o fi i ṣe ere fifin ati ere didà: o si wà ni ile Mika.
5 Ọkunrin na Mika si ní ile-oriṣa kan, o si ṣe efodu, ati terafimu, o si yà ọkan ninu awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin sọtọ̀, ẹniti o si wa di alufa rẹ̀.
6 Li ọjọ́ wọnni ọba kan kò sí ni Israeli: olukuluku enia nṣe eyiti o tọ́ li oju ara rẹ̀.
7 Ọmọkunrin kan si ti Beti-lehemu-juda wá, ti iṣe idile Juda, ẹniti iṣe ẹ̀ya Lefi, on si ṣe atipo nibẹ̀.
8 Ọkunrin na si ti ilu Beti-lehemu-juda lọ, lati ṣe atipo nibikibi ti o ba ri: on si dé ilẹ òke Efraimu si ile Mika, bi o ti nlọ.
9 Mika si wi fun u pe, Nibo ni iwọ ti wá? On si wi fun u pe, Ẹ̀ya Lefi ti Beti-lehemu-juda li emi iṣe, emi si nlọ ṣe atipo nibikibi ti emi ba ri.