6 Li ọjọ́ wọnni ọba kan kò sí ni Israeli: olukuluku enia nṣe eyiti o tọ́ li oju ara rẹ̀.
7 Ọmọkunrin kan si ti Beti-lehemu-juda wá, ti iṣe idile Juda, ẹniti iṣe ẹ̀ya Lefi, on si ṣe atipo nibẹ̀.
8 Ọkunrin na si ti ilu Beti-lehemu-juda lọ, lati ṣe atipo nibikibi ti o ba ri: on si dé ilẹ òke Efraimu si ile Mika, bi o ti nlọ.
9 Mika si wi fun u pe, Nibo ni iwọ ti wá? On si wi fun u pe, Ẹ̀ya Lefi ti Beti-lehemu-juda li emi iṣe, emi si nlọ ṣe atipo nibikibi ti emi ba ri.
10 Mika si wi fun u pe, Bá mi joko, ki iwọ ki o ma ṣe baba ati alufa fun mi, emi o ma fi owo fadakà mẹwa fun ọ li ọdún, adápe aṣọ kan, ati onjẹ rẹ. Bẹ̃ni ọmọ Lefi na si wọle.
11 O si rọ̀ ọmọ Lefi na lọrùn lati bá ọkunrin na joko; ọmọkunrin na si wà lọdọ rẹ̀ bi ọkan ninu awọn ọmọ rẹ̀.
12 Mika si yà ọmọ Lefi na sọ̀tọ, ọmọkunrin na si wa di alufa rẹ̀, o si wà ninu ile Mika.