3 Ọkọ rẹ̀ si dide, o si tọ̀ ọ lọ, lati tù u ninu, ati lati mú u pada, ọmọ-ọdọ rẹ̀ si mbẹ pẹlu rẹ̀, ati kẹtẹkẹtẹ meji: ọmọbinrin na si mú u wá sinu ile baba rẹ̀: nigbati baba rẹ̀ si ri i, o yọ̀ lati pade rẹ̀.
4 Ana rẹ̀, baba ọmọbinrin na, si da a duro; o si bá a joko ni ijọ́ mẹta; nwọn jẹ nwọn mu, nwọn si wọ̀ nibẹ̀.
5 O si ṣe ni ijọ́ kẹrin, nwọn jí ni kùtukutu, o si dide lati lọ: baba ọmọbinrin na si wi fun ana rẹ̀ pe, Fi òkele onjẹ kan tẹlẹ inu, lẹhin na ki ẹ ma lọ.
6 Nwọn si joko, awọn mejeji si jùmọ jẹ, nwọn si mu: baba ọmọbinrin na si wi fun ọkunrin na pe, Mo bẹ̀ ọ, farabalẹ, ki o si duro li oru oni, ki o si jẹ ki inu rẹ ki o dùn.
7 Nigbati ọkunrin na si dide lati lọ, ana rẹ̀ si rọ̀ ọ, o si tun sùn sibẹ̀.
8 On si dide ni kùtukutu ọjọ́ karun lati lọ, baba ọmọbinrin na si wipe, Mo bẹ̀ ọ, tù ara rẹ lara, ki ẹ si duro titi di irọlẹ; awọn mejeji si jẹun.
9 Nigbati ọkunrin na si dide lati lọ, on, ati àle rẹ̀, ati ọmọ-ọdọ rẹ̀, ana rẹ̀, baba ọmọbinrin na, si wi fun u pe, Kiyesi i nisisiyi, ọjọ́ di aṣalẹ tán, emi bẹ̀ ọ duro li oru yi: kiyesi i ọjọ́ lọ tán, sùn sihin, ki inu rẹ ki o le dùn: ni kùtukutu ọla ẹ tète bọ́ si ọ̀na nyin, ki iwọ ki o le lọ ile.