8 On si dide ni kùtukutu ọjọ́ karun lati lọ, baba ọmọbinrin na si wipe, Mo bẹ̀ ọ, tù ara rẹ lara, ki ẹ si duro titi di irọlẹ; awọn mejeji si jẹun.
9 Nigbati ọkunrin na si dide lati lọ, on, ati àle rẹ̀, ati ọmọ-ọdọ rẹ̀, ana rẹ̀, baba ọmọbinrin na, si wi fun u pe, Kiyesi i nisisiyi, ọjọ́ di aṣalẹ tán, emi bẹ̀ ọ duro li oru yi: kiyesi i ọjọ́ lọ tán, sùn sihin, ki inu rẹ ki o le dùn: ni kùtukutu ọla ẹ tète bọ́ si ọ̀na nyin, ki iwọ ki o le lọ ile.
10 Ọkunrin na si kọ̀ lati sùn, o si dide o si lọ, o si dé ọkankan Jebusi (ti iṣe Jerusalemu): kẹtẹkẹtẹ meji ti a dì ni gãri wà lọdọ rẹ̀, àle rẹ̀ pẹlu si wà lọdọ rẹ̀.
11 Nigbati nwọn si dé eti Jebusi, ọjọ́ lọ tán; ọmọ-ọdọ na si wi fun oluwa rẹ̀ pe, Wá, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki a yà si ilu Jebusi yi, ki a si wọ̀ sibẹ̀.
12 Oluwa rẹ̀ si wi fun u pe, Awa ki o yà si ilu ajeji kan, ti ki iṣe ti awọn ọmọ Israeli; awa o rekọja si Gibea.
13 On si wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Wá jẹ ki a sunmọ ọkan ninu ibi wọnyi; ki a si wọ̀ si Gibea, tabi Rama.
14 Nwọn si rekọja, nwọn lọ: õrùn si wọ̀ bá wọn leti Gibea, ti iṣe ti Benjamini.