7 Awọn ọmọ Israeli si ṣe eyiti o buru li oju OLUWA, nwọn si gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn, nwọn si nsìn Baalimu ati Aṣerotu.
8 Nitori na ibinu OLUWA ru si Israeli, o si tà wọn si ọwọ́ Kuṣani-riṣataimu ọba Mesopotamia: awọn ọmọ Israeli si sìn Kuṣani-riṣataimu li ọdún mẹjọ.
9 Nigbati awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA, OLUWA si gbé olugbala kan dide fun awọn ọmọ Israeli, ẹniti o gbà wọn, ani Otnieli ọmọ Kenasi, aburò Kalebu.
10 Ẹmi OLUWA si wà lara rẹ̀, on si ṣe idajọ Israeli, o si jade ogun, OLUWA si fi Kuṣani-riṣataimu ọba Mesopotamia lé e lọwọ: ọwọ́ rẹ̀ si bori Kuṣani-riṣataimu.
11 Ilẹ na si simi li ogoji ọdún. Otnieli ọmọ Kenasi si kú.
12 Awọn ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti o buru loju OLUWA: OLUWA si fi agbara fun Egloni ọba Moabu si Israeli, nitoripe nwọn ti ṣe eyiti o buru li oju OLUWA.
13 O si kó awọn ọmọ Ammoni ati ti Amaleki mọra rẹ̀; o si lọ o kọlù Israeli, nwọn si gbà ilu ọpẹ.