17 Ṣugbọn Sisera ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sálọ si agọ́ Jaeli aya Heberi ọmọ Keni: nitoriti alafia wà lãrin Jabini ọba Hasori ati ile Heberi ọmọ Keni.
18 Jaeli si jade lọ ipade Sisera, o si wi fun u pe, Yà wá, oluwa mi, yà sọdọ mi; má bẹ̀ru. On si yà sọdọ rẹ̀ sinu agọ́, o si fi kubusu bò o.
19 On si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, fun mi li omi diẹ mu; nitoriti ongbẹ ngbẹ mi. O si ṣí igo warà kan, o si fi fun u mu, o si bò o lara.
20 On si wi fun u pe, Duro li ẹnu-ọ̀na agọ́, yio si ṣe, bi ẹnikan ba wá, ti o si bi ọ lère pe, ọkunrin kan wà nihin bi? ki iwọ wipe, Kò sí.
21 Nigbana ni Jaeli aya Heberi mú iṣo-agọ́ kan, o si mú õlù li ọwọ́ rẹ̀, o si yọ́ tọ̀ ọ, o si kàn iṣo na mọ́ ẹbati rẹ̀, o si wọ̀ ilẹ ṣinṣin; nitoriti o sùn fọnfọn; bẹ̃ni o daku, o si kú.
22 Si kiyesi i, bi Baraki ti nlepa Sisera, Jaeli wá pade, rẹ̀, o si wi fun u pe, Wá, emi o si fi ọkunrin ti iwọ nwá hàn ọ. O si wá sọdọ rẹ̀; si kiyesi i, Sisera dubulẹ li okú, iṣo-agọ́ na si wà li ẹbati rẹ̀.
23 Bẹ̃li Ọlọrun si tẹ̀ ori Jabini ọba Kenaani ba li ọjọ́ na niwaju awọn ọmọ Israeli.