2 OLUWA si tà wọn si ọwọ́ Jabini ọba Kenaani, ẹniti o jọba ni Hasori; olori ogun ẹniti iṣe Sisera, ẹniti ngbé Haroṣeti ti awọn orilẹ-ède.
3 Awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA: nitoriti o ní ẹdẹgbẹrun kẹkẹ́ irin; ogun ọdún li o si fi pọ́n awọn ọmọ Israeli loju gidigidi.
4 Ati Debora, wolĩ-obinrin, aya Lappidotu, o ṣe idajọ Israeli li akokò na.
5 On si ngbé abẹ igi-ọpẹ Debora li agbedemeji Rama ati Beti-eli ni ilẹ òke Efraimu: awọn ọmọ Israeli a si ma wá sọdọ rẹ̀ fun idajọ.
6 On si ranṣẹ pè Baraki ọmọ Abinoamu lati Kedeṣi-naftali jade wá, o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun Israeli kò ha ti paṣẹ pe, Lọ sunmọ òke Tabori, ki o si mú ẹgba marun ọkunrin ninu awọn ọmọ Naftali, ati ninu awọn ọmọ Sebuluni pẹlu rẹ.
7 Emi o si fà Sisera, olori ogun Jabini, pẹlu kẹkẹ́ rẹ̀ ati ogun rẹ̀, sọdọ rẹ si odò Kiṣoni; emi o si fi i lé ọ lọwọ.
8 Baraki si wi fun u pe, Bi iwọ o ba bá mi lọ, njẹ emi o lọ: ṣugbọn bi iwọ ki yio ba bá mi lọ, emi ki yio lọ.