32 Nitorina li ọjọ́ na, o pè orukọ rẹ̀ ni Jerubbaali, wipe, Jẹ ki Baali ki o bá a jà, nitoriti o wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ.
33 Nigbana ni gbogbo awọn Midiani ati awọn Amaleki, ati awọn ọmọ ìha ìla-õrùn kó ara wọn jọ pọ̀; nwọn rekọja, nwọn si dó li afonifoji Jesreeli.
34 Ṣugbọn ẹmi OLUWA bà lé Gideoni, on si fun ipè; Abieseri si kójọ sẹhin rẹ̀.
35 On si rán onṣẹ si gbogbo Manasse; awọn si kójọ sẹhin rẹ̀ pẹlu: o si rán onṣẹ si Aṣeri, ati si Sebuluni, ati si Naftali; nwọn si gòke wá lati pade wọn.
36 Gideoni si wi fun Ọlọrun pe, Bi iwọ o ba ti ọwọ́ mi gbà Israeli là, bi iwọ ti wi,
37 Kiyesi i, emi o fi irun agutan le ilẹ-pakà; bi o ba ṣepe ìri sẹ̀ sara kìki irun nikan, ti gbogbo ilẹ si gbẹ, nigbana li emi o mọ̀ pe iwọ o ti ọwọ́ mi gbà Israeli là, gẹgẹ bi iwọ ti wi.
38 Bẹ̃li o si ri: nitoriti on dide ni kùtukutu ijọ́ keji, o si fọ́n irun agutan na, o si fọ́n ìri na kuro lara rẹ̀, ọpọ́n kan si kún fun omi.