27 Gideoni si fi i ṣe ẹ̀wu-efodu kan, o si fi i si ilu rẹ̀, ni Ofra: gbogbo Israeli si ṣe àgbere tọ̀ ọ lẹhin nibẹ̀: o si wa di idẹkun fun Gideoni, ati fun ile rẹ̀.
28 Bẹ̃li a si tẹ̀ ori Midiani ba niwaju awọn ọmọ Israeli, nwọn kò si gbé ori wọn soke mọ́. Ilẹ na si simi ni ogoji ọdún li ọjọ́ Gideoni.
29 Jerubbaali ọmọ Joaṣi si lọ o si ngbe ile rẹ̀.
30 Gideoni si ní ãdọrin ọmọkunrin ti o bi fun ara rẹ̀: nitoripe o lí obinrin pupọ̀.
31 Ale rẹ̀ ti o wà ni Ṣekemu, on pẹlu bi ọmọkunrin kan fun u, orukọ ẹniti a npè ni Abimeleki.
32 Gideoni ọmọ Joaṣi si kú li ọjọ́ ogbó, a si sin i si ibojì Joaṣi baba rẹ̀, ni Ofra ti awọn Abieseri.
33 O si ṣe, lojukanna ti Gideoni kú, li awọn ọmọ Israeli pada, nwọn si ṣe panṣaga tọ̀ Baalimu lọ, nwọn si fi Baaliberiti ṣe oriṣa wọn.