8 Oluwa, tiwa ni itiju, ti awọn ọba wa, ati awọn olori wa, ati ti awọn baba wa, nitori ti awa ti ṣọ̀tẹ si ọ.
9 Sibẹ ti Oluwa Ọlọrun wa li ãnu ati idariji bi awa tilẹ ṣọ̀tẹ si i;
10 Bẹ̃li awa kò si gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́, lati ma rìn nipa ofin ti o gbé kalẹ niwaju wa lati ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli wá.
11 Bẹ̃ni gbogbo Israeli ti ṣẹ̀ si ofin rẹ, ani nipa kikuro, ki nwọn ki o máṣe gbà ohùn rẹ gbọ́; nitorina li a ṣe yi egún dà si ori wa, ati ibura na ti a kọ sinu ofin Mose, iranṣẹ Ọlọrun, nitori ti awa ti ṣẹ̀ si i.
12 On si mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ, eyi ti o sọ si wa, ati si awọn onidajọ wa ti o nṣe idajọ fun wa, nipa eyi ti o fi mu ibi nla bá wa: iru eyi ti a kò ti iṣe si gbogbo abẹ ọrun, gẹgẹ bi a ti ṣe sori Jerusalemu.
13 Gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin Mose, gbogbo ibi wọnyi wá sori wa: bẹ̃li awa kò si wá ojurere niwaju Oluwa, Ọlọrun wa, ki awa ki o le yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ wa, ki a si moye otitọ rẹ.
14 Nitorina li Oluwa ṣe fiyesi ibi na, ti o si mu u wá sori wa; nitoripe olododo li Oluwa Ọlọrun wa ni gbogbo iṣẹ rẹ̀ ti o nṣe: ṣugbọn awa kò gbà ohùn rẹ̀ gbọ́.