1 NIGBATI oṣu keje si pé, ti awọn ọmọ Israeli si wà ninu ilu wọnni, awọn enia na ko ara wọn jọ pọ̀ bi ẹnikan si Jerusalemu.
2 Jeṣua ọmọ Jehosadaki si dide pẹlu awọn arakunrin rẹ̀ awọn alufa, ati Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, ati awọn arakunrin rẹ̀, nwọn si tẹ́ pẹpẹ Ọlọrun Israeli, lati ma ru ẹbọ ọrẹ sisun lori rẹ̀, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin Mose, enia Ọlọrun.
3 Nwọn si gbe pẹpẹ na ka ipilẹ rẹ̀; nitori ẹ̀ru bà wọn nitori awọn enia ilẹ wọnni. Nwọn si rú ẹbọ ọrẹ sisun si Oluwa, ọrẹ ẹbọ sisun li owurọ ati li aṣalẹ.
4 Nwọn si pa àse agọ mọ pẹlu, gẹgẹ bi a ti kọ ọ, nwọn si rú ẹbọ sisun ojojumọ pẹlu nipa iye ti a pa li aṣẹ, gẹgẹ bi isin ojojumọ;