16 Awa mu u da ọba li oju pe, bi a ba tun ilu yi kọ, ti a si pari odi rẹ̀ nipa ọ̀na yi, iwọ kì o ni ipin mọ ni ihahin odò.
17 Nigbana ni ọba fi èsi ranṣẹ si Rehumu, adele-ọba, ati si Ṣimṣai, akọwe, pẹlu awọn ẹgbẹ wọn iyokù ti ngbe Samaria, ati si awọn iyokù li oke odò: Alafia! ati kiki miran.
18 A kà iwe ti ẹnyin fi ranṣẹ si wa dajudaju niwaju mi.
19 Mo si paṣẹ, a si ti wá, a si ri pe, lati atijọ wá, ilu yi a ti ma ṣọ̀tẹ si awọn ọba, ati pe irukerudo ati ọ̀tẹ li a ti nṣe ninu rẹ̀.
20 Pẹlupẹlu awọn ọba alagbara li o ti wà lori Jerusalemu, awọn ti o jọba lori gbogbo ilu oke-odò; owo ori, owo odè, ati owo bodè li a ti nsan fun wọn.
21 Ki ẹnyin ki o paṣẹ nisisiyi lati mu awọn ọkunrin wọnyi ṣiwọ, ki a má si kọ ilu na mọ, titi aṣẹ yio fi jade lati ọdọ mi wá.
22 Ẹ kiyesi ara nyin, ki ẹnyin ki o má jafara lati ṣe eyi: ẽṣe ti ìbajẹ yio fi ma dàgba si ipalara awọn ọba?