4 Nigbana ni awọn enia ilẹ na mu ọwọ awọn enia Juda rọ, nwọn si yọ wọn li ẹnu ninu kikọle na.
5 Nwọn si bẹ̀ awọn ìgbimọ li ọ̀wẹ si wọn, lati sọ ipinnu wọn di asan, ni gbogbo ọjọ Kirusi, ọba Persia, ani titi di ijọba Dariusi, ọba Persia.
6 Ati ni ijọba Ahasuerusi, ni ibẹ̀rẹ ijọba rẹ̀, ni nwọn kọwe ẹ̀sun lati fi awọn ara Juda ati Jerusalemu sùn.
7 Ati li ọjọ Artasasta ni Biṣlami, Mitredati, Tabeeli ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ iyokù kọwe si Artasasta, ọba Persia: a si kọ iwe na li ède Siria, a si ṣe itumọ rẹ̀ li ède Siria.
8 Rehumu, adele ọba, ati Ṣimṣai, akọwe, kọ iwe ẹ̀sun Jerusalemu si Artasasta ọba, bi iru eyi:
9 Nigbana ni Rehumu, adele-ọba, ati Ṣimṣai akọwe, ati awọn ẹgbẹ wọn iyokù: awọn ara Dina, ti Afarsatki, ti Tarpeli, ti Afarsi, ti Arkefi, ti Babiloni, ti Susanki, ti Dehafi ati ti Elamu,
10 Ati awọn orilẹ-ède iyokù ti Asnapperi, ọlọla ati ẹni-nla nì, kó rekọja wá, ti o si fi wọn do si ilu Samaria, ati awọn iyokù ti o wà ni ihahin odò, ati ẹlomiran.