11 Eyi si ni atunkọ iwe na ti Artasasta ọba fi fun Esra alufa, akọwe, ani akọwe ọ̀rọ ofin Oluwa, ati ti aṣẹ rẹ̀ fun Israeli.
12 Artasasta, ọba awọn ọba, si Esra alufa, akọwe pipé ti ofin Ọlọrun ọrun, alafia:
13 Mo paṣẹ pe, ki gbogbo enia ninu awọn enia Israeli, ati ninu awọn alufa rẹ̀ ati awọn ọmọ Lefi, ninu ijọba mi, ẹniti o ba fẹ nipa ifẹ inu ara wọn lati gòkẹ lọ si Jerusalemu, ki nwọn ma ba ọ lọ.
14 Niwọn bi a ti rán ọ lọ lati iwaju ọba lọ ati ti awọn ìgbimọ rẹ̀ mejeje, lati wadi ọ̀ran ti Juda ati Jerusalemu gẹgẹ bi ofin Ọlọrun rẹ ti mbẹ li ọwọ rẹ;
15 Ati lati ko fàdaka ati wura, ti ọba ati awọn ìgbimọ fi tinutinu fi fun Ọlọrun Israeli, ibugbe ẹniti o wà ni Jerusalemu.
16 Ati gbogbo fàdaka ati wura ti iwọ le ri ni gbogbo igberiko Babiloni, pẹlu ọrẹ atinuwa awọn enia, ati ti awọn alufa, ti iṣe ọrẹ atinuwa fun ile Ọlọrun wọn ti o wà ni Jerusalemu.
17 Ki iwọ ki o le fi owo yi rà li aijafara, akọmalu, àgbo, ọdọ-agutan, ati ọrẹ ohun jijẹ wọn ati ọrẹ ohun mimu wọn, ki o si fi wọn rubọ li ori pẹpẹ ile Ọlọrun nyin ti o wà ni Jerusalemu.