13 Ọba si bi awọn ọlọgbọ́n, ti nwọn moye akokò, (nitori bẹ̃ni ìwa ọba ri si gbogbo awọn ti o mọ̀ ofin ati idajọ:
14 Awọn ti o sunmọ ọ ni Karṣina, Ṣetari, Admata, Tarṣiṣi, Meresi, Marsena, ati Memukani, awọn ijoye Persia ati Media mejeje, ti nri oju ọba, ti nwọn si joko ni ipò ikini ni ijọba).
15 Pe, gẹgẹ bi ofin, Kini ki a ṣe si Faṣti ayaba, nitoriti on kò ṣe bi Ahaswerusi ọba ti paṣẹ fun u, lati ọwọ awọn ìwẹfa rẹ̀ wá?
16 Memukani si dahùn niwaju ọba ati awọn ijoye pe, Faṣti ayaba kò ṣẹ̀ si ọba nikan, ṣugbọn si gbogbo awọn ijoye, ati si gbogbo awọn enia ti o wà ni ìgberiko Ahaswerusi ọba.
17 Nitori ìwa ayaba yi yio tàn de ọdọ gbogbo awọn obinrin, tobẹ̃ ti ọkọ wọn yio di gigàn loju wọn, nigbati a o sọ ọ wi pe, Ahaswerusi ọba paṣẹ pe, ki a mu Faṣti ayaba wá siwaju rẹ̀, ṣugbọn on kò wá.
18 Awọn ọlọla-obinrin Persia ati Media yio si ma wi bakanna li oni yi fun gbogbo awọn ijoye ọba ti nwọn gbọ́ ìwa ti ayaba hù. Bayi ni ẹ̀gan pipọ̀-pipọ̀, ati ibinu yio dide.
19 Bi o ba dara loju ọba, ki aṣẹ ọba ki o ti ọdọ rẹ̀ lọ, ki a si kọ ọ pẹlu awọn ofin Persia ati Media, ki a má ṣe le pa a dà, pe, ki Faṣti ki o máṣe wá siwaju Ahaswerusi ọba mọ, ki ọba ki o si fi oyè ayaba rẹ̀ fun ẹgbẹ rẹ̀ ti o san jù u lọ.