1 O si ṣe li ọjọ kẹta, ni Esteri wọ̀ aṣọ ayaba rẹ̀, o si duro ni àgbala ile ọba ti o wà ninu, lọgangan ile ọba: ọba si joko lori ìtẹ ijọba rẹ̀ ni ile ọba, ti o kọjusi ẹnu-ọ̀na ile na.
2 O si ṣe nigbati ọba ri ti Esteri ayaba duro ni àgbala, on si ri ore-ọfẹ loju rẹ̀: ọba si nà ọ̀pá alade wura ti o wà lọwọ rẹ̀ si Esteri. Esteri si sunmọ ọ, o si fi ọwọ kàn ori ọpá alade na.
3 Nigbana ni ọba bi i pe, kini iwọ nfẹ́, Esteri ayaba? ati kini ẹ̀bẹ rẹ̀? ani de idajì ijọba li a o si fi fun ọ.
4 Esteri si dahùn pe, bi o ba dara loju ọba, jẹ ki ọba ati Hamani ki o wá loni si àse mi, ti mo ti mura silẹ fun u.
5 Nigbana ni ọba wi pe, ẹ mu ki Hamani ki o yara, ki on ki o le ṣe bi Esteri ti wi. Bẹ̃ni ọba ati Hamani wá si àse na ti Esteri ti sè silẹ.
6 Ọba si wi fun Esteri nibiti nwọn gbe nmu ọti-waini pe, kini ibere rẹ? a o si fi fun ọ: ki si ni ẹ̀bẹ rẹ? ani de idajì ijọba, a o si ṣe e.