21 Ẹnyin kò le mu ago Oluwa ati ago awọn ẹmi èṣu: ẹnyin kò le ṣe ajọpin ni tabili Oluwa, ati ni tabili awọn ẹmi èṣu.
22 Awa ha nmu Oluwa jowú bi? awa ha li agbara jù u lọ?
23 Ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn ki iṣe ohun gbogbo li o li ere; ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn kì iṣe ohun gbogbo ni igbé-ni-ró.
24 Ki ẹnikẹni máṣe mã wá ti ara rẹ̀, ṣugbọn ki olukuluku mã wá ire ọmọnikeji rẹ̀.
25 Ohunkohun ti a ba ntà li ọjà ni ki ẹ mã jẹ, laibere ohun kan nitori ẹri-ọkàn.
26 Nitoripe ti Oluwa ni ilẹ ati ẹkún rẹ̀.
27 Bi ọkan ninu awọn ti kò gbagbọ́ ba pè nyin sibi àse, bi ẹnyin ba si fẹ ilọ; ohunkohun ti a ba gbé kalẹ niwaju nyin ni ki ẹ jẹ, laibere ohun kan nitori ẹri-ọkàn.