13 Mo si gbọ́ ohùn kan lati ọrun wá nwi fun mi pe, Kọwe rẹ̀, Alabukún fun li awọn okú ti o kú nipa ti Oluwa lati ìhin lọ: Bẹni, li Ẹmí wi, ki nwọn ki o le simi kuro ninu lãlã wọn, nitori iṣẹ wọn ntọ̀ wọn lẹhin.
14 Mo si wò, si kiyesi i, awọsanma funfun kan, ati lori awọsanma na ẹnikan joko ti o dabi Ọmọ-enia, ti on ti ade wura li ori rẹ̀, ati dòjé mimú li ọwọ́ rẹ̀.
15 Angẹli miran si ti inu tẹmpili jade wá ti nke li ohùn rara si ẹniti o joko lori awọsanma pe, Tẹ̀ doje rẹ bọ̀ ọ, ki o si mã kore: nitori akokò ati kore de, nitori ikorè aiye ti gbó tan.
16 Ẹniti o joko lori awọsanma na si tẹ̀ doje rẹ̀ bọ̀ ori ilẹ aiye; a si ṣe ikore ilẹ aiye.
17 Angẹli miran si ti inu tẹmpili ti mbẹ li ọrun jade wá, ti on ti doje mimu.
18 Angẹli miran si ti ibi pẹpẹ jade wá, ti o ni agbara lori iná; o si ke li ohùn rara si ẹniti o ni doje mimu, wipe, Tẹ̀ doje rẹ mimu bọ̀ ọ, ki o si rẹ́ awọn idi ajara aiye, nitori awọn eso rẹ̀ ti pọ́n.
19 Angẹli na si tẹ̀ doje rẹ̀ bọ̀ ilẹ aiye, o si ké ajara ilẹ aiye, o si kó o lọ sinu ifúnti, ifúnti nla ibinu Ọlọrun.