16 Ẹniti o joko lori awọsanma na si tẹ̀ doje rẹ̀ bọ̀ ori ilẹ aiye; a si ṣe ikore ilẹ aiye.
17 Angẹli miran si ti inu tẹmpili ti mbẹ li ọrun jade wá, ti on ti doje mimu.
18 Angẹli miran si ti ibi pẹpẹ jade wá, ti o ni agbara lori iná; o si ke li ohùn rara si ẹniti o ni doje mimu, wipe, Tẹ̀ doje rẹ mimu bọ̀ ọ, ki o si rẹ́ awọn idi ajara aiye, nitori awọn eso rẹ̀ ti pọ́n.
19 Angẹli na si tẹ̀ doje rẹ̀ bọ̀ ilẹ aiye, o si ké ajara ilẹ aiye, o si kó o lọ sinu ifúnti, ifúnti nla ibinu Ọlọrun.
20 A si tẹ̀ ifúnti na lẹhin odi ilu na, ẹ̀jẹ si ti inu ifúnti na jade, ani ti o tó okùn ijanu ẹṣin jinna to ẹgbẹjọ furlongi.