3 Nwọn si nkọ bi ẹnipe orin titun niwaju itẹ́ nì, ati niwaju awọn ẹda alãye mẹrin nì, ati awọn àgba nì: ko si si ẹniti o le kọ́ orin na, bikoṣe awọn ọkẹ́ meje o le ẹgbaji enia, ti a ti rà pada lati inu aiye wá.
4 Awọn wọnyi li a kò fi obinrin sọ di ẽri; nitoripe wundia ni nwọn. Awọn wọnyi ni ntọ̀ Ọdọ-Agutan na lẹhin nibikibi ti o ba nlọ. Awọn wọnyi li a rà pada lati inu awọn enia wá, nwọn jẹ́ akọso fun Ọlọrun ati fun Ọdọ-Agutan na.
5 A kò si ri eke li ẹnu wọn, nwọn jẹ alailabuku.
6 Mo si ri angẹli miran nfò li agbedemeji ọrun, ti on ti ihinrere ainipẹkun lati wãsu fun awọn ti ngbé ori ilẹ aiye, ati fun gbogbo orilẹ, ati ẹya, ati ède, ati enia,
7 O nwi li ohùn rara pe, Ẹ bẹ̀ru Ọlọrun, ki ẹ si fi ogo fun u; nitoriti wakati idajọ rẹ̀ de: ẹ si foribalẹ fun ẹniti o dá ọrun, on aiye, ati okun, ati awọn orisun omi.
8 Angẹli miran si tẹ̀le e, o nwipe, Babiloni wó, Babiloni ti o tobi nì wó, eyiti o ti nmú gbogbo orilẹ-ède mu ninu ọti-waini ibinu àgbere rẹ̀.
9 Angẹli kẹta si tẹle wọn, o nwi li ohùn rara pe, Bi ẹnikẹni ba nforibalẹ fun ẹranko nì, ati aworan rẹ̀, ti o si gbà àmi si iwaju rẹ̀ tabi si ọwọ́-rẹ̀,