10 Nwọn o duro li okere rére nitori ibẹru iṣẹ oró rẹ̀, nwọn o mã wipe, Egbé, Egbé ni fun ilu nla na, Babiloni, ilu alagbara ni! nitori ni wakati kan ni idajọ rẹ de.
11 Awọn oniṣowo aiye si nsọkun, nwọn si nṣọ̀fọ lori rẹ̀; nitoripe ẹnikẹni kò rà ọjà wọn mọ́:
12 Ọjà wura, ati ti fadaka, ati ti okuta iyebiye, ati ti perli, ati ti aṣọ ọgbọ wíwe, ati ti elese aluko, ati ti ṣẹ́dà, ati ti ododó, ati ti gbogbo igi olõrun didun, ati ti olukuluku ohun èlo ti ehin-erin, ati ti olukuluku ohun èlo ti a fi igi iyebiye ṣe, ati ti idẹ, ati ti irin, ati ti okuta marbili,
13 Ati ti kinamoni, ati ti oniruru ohun olõrun didun, ati ti ohun ikunra, ati ti turari, ati ti ọti-waini, ati ti oróro, ati ti iyẹfun daradara, ati ti alikama, ati ti ẹranlá, ati ti agutan, ati ti ẹṣin, ati ti kẹkẹ́, ati ti ẹrú, ati ti ọkàn enìa.
14 Ati awọn eso ti ọkàn rẹ nṣe ifẹkufẹ si, sì lọ kuro lọdọ rẹ, ati ohun gbogbo ti o dùn ti o si dara ṣegbe mọ ọ loju, a kì yio si tún ri wọn mọ́ lai.
15 Awọn oniṣowo nkan wọnyi, ti a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọrọ̀, yio duro li òkere rére nitori ìbẹru iṣẹ oró rẹ̀, nwọn o mã sọkun, nwọn o si mã ṣọ̀fọ,
16 Wipe, Ègbé, egbé ni fun ilu nla nì, ti a wọ̀ li aṣọ ọgbọ wíwẹ, ati ti elese aluko, ati ti ododó, ati ti a si fi wura ṣe lọṣọ́, pẹlu okuta iyebiye ati perli!