1 O si fi odò omi ìye kan han mi, ti o mọ́ bi kristali, ti nti ibi itẹ́ Ọlọrun ati ti Ọdọ-Agutan jade wá.
2 Li ãrin igboro rẹ̀, ati niha ikini keji odò na, ni igi iye gbé wà, ti ima so onirũru eso mejila, a si mã so eso rẹ̀ li oṣõṣù: ewé igi na si ni fún mimú awọn orilẹ-ède larada.
3 Ègún kì yio si si mọ́: itẹ́ Ọlọrun ati ti Ọdọ-Agutan ni yio si mã wà nibẹ̀; awọn iranṣẹ rẹ̀ yio si ma sìn i:
4 Nwọn o si mã ri oju rẹ̀; orukọ rẹ̀ yio si mã wà ni iwaju wọn.
5 Oru kì yio si si mọ́; nwọn kò si ni iwá imọlẹ fitila, tabi imọlẹ õrùn; nitoripe Oluwa Ọlọrun ni yio tan imọlẹ fun wọn: nwọn o si mã jọba lai ati lailai.
6 O si wi fun mi pe, ododo ati otitọ li ọ̀rọ wọnyi: Oluwa Ọlọrun ẹmi awọn woli li o si rán angẹli rẹ̀ lati fi ohun ti kò le ṣaiṣẹ kánkán hàn awọn iranṣẹ rẹ̀.