1 PAULU Aposteli Jesu Kristi nipa ifẹ Ọlọrun, ati Timotiu arakunrin wa, si ijọ Ọlọrun ti o wà ni Korinti, pẹlu, gbogbo awọn enia mimọ́ ti o wà ni gbogbo Akaia:
2 Õre-ọfẹ si nyin ati alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa.
3 Olubukún li Ọlọrun, ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Baba iyọ́nu, ati Ọlọrun itunu gbogbo;
4 Ẹniti ntù wa ninu ni gbogbo wahalà wa, nipa itunu na ti a fi ntù awa tikarawa ninu lati ọdọ Ọlọrun wá, ki awa ki o le mã tù awọn ti o wà ninu wahala-ki-wahala ninu.