2. Kor 3 YCE

Òjíṣẹ́ Majẹmu Titun

1 AWA ha tún bẹ̀rẹ lati mã yìn ara wa bi? tabi awa ha nfẹ iwe iyìn sọdọ nyin, tabi lati ọdọ nyin bi awọn ẹlomiran?

2 Ẹnyin ni iwe wa, ti a ti kọ si wa li ọkàn, ti gbogbo enia ti mọ̀, ti nwọn sì ti kà:

3 Bi a ti fi nyin hàn pe, iwe Kristi ni nyin, ti a nṣe iranṣẹ fun, kì iṣe eyiti a fi tadawa kọ, bikoṣe Ẹmí Ọlọrun alãye; kì iṣe ninu tabili okuta, bikoṣe ninu tabili ọkàn ẹran.

4 Irú igbẹkẹle yi li awa si ni nipa Kristi sọdọ Ọlọrun:

5 Kì iṣe pe awa to fun ara wa lati ṣirò ohunkohun bi ẹnipe lati ọdọ awa tikarawa; ṣugbọn lati ọdọ Ọlọrun ni tito wa;

6 Ẹniti o mu wa tó bi iranṣẹ majẹmu titun; kì iṣe ti iwe, bikoṣe ti ẹmí: nitori iwe a mã pani, ṣugbọn ẹmí a mã sọni di ãye.

7 Ṣugbọn bi iṣẹ-iranṣẹ ti ikú, ti a ti kọ ti a si ti gbẹ́ si ara okuta, ba jẹ ologo, tobẹ̃ ti awọn ọmọ Israeli kò le tẹjumọ ati wò oju Mose, nitori ogo oju rẹ̀ (ogo nkọja lọ),

8 Yio ha ti ri ti iṣẹ-iranṣẹ ti ẹmí kì yio kuku jẹ ogo jù?

9 Nitoripe bi iṣẹ-iranṣẹ idalẹbi ba jẹ ologo, melomelo ni iṣẹ-iranṣẹ ododo yio rekọja li ogo.

10 Nitori eyi ti a tilẹ ṣe logo, kò li ogo mọ́ nitori eyi, nipasẹ ogo ti o tayọ.

11 Nitoripe bi eyi ti nkọja lọ ba li ogo, melomelo li eyi ti o duro li ogo.

12 Njẹ nitorina bi a ti ni irú ireti bi eyi, awa nfi igboiya pupọ sọ̀rọ.

13 Kì si iṣe bi Mose, ẹniti o fi iboju bo oju rẹ̀, ki awọn ọmọ Israeli má ba le tẹjumọ wo opin eyi ti nkọja lọ.

14 Ṣugbọn oju-inu wọn fọ́: nitoripe titi fi di oni oloni ní kika majẹmu lailai, iboju na wà laiká soke; iboju ti a ti mu kuro ninu Kristi.

15 Ṣugbọn titi di oni oloni, nigbakugba ti a ba nkà Mose, iboju na mbẹ li ọkàn wọn.

16 Ṣugbọn nigbati on o ba yipada si Oluwa, a o mu iboju na kuro.

17 Njẹ Oluwa li Ẹmí na: nibiti Ẹmí Oluwa ba si wà, nibẹ̀ li omnira gbé wà.

18 Ṣugbọn gbogbo wa nwò ogo Oluwa laisi iboju bi ẹnipe ninu awojiji, a si npawada si aworan kanna lati ogo de ogo, ani bi lati ọdọ Oluwa ti iṣe Ẹmí.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13