2. Kor 5 YCE

1 NITORI awa mọ̀ pe, bi ile agọ́ wa ti aiye bá wó, awa ni ile kan lati ọdọ Ọlọrun, ile ti a kò fi ọwọ́ kọ́, ti aiyeraiye ninu awọn ọrun.

2 Nitori nitõtọ awa nkerora ninu eyi, awa si nfẹ gidigidi lati fi ile wa lati ọrun wá wọ̀ wa:

3 Bi o ba ṣepe a ti wọ̀ wa li aṣọ, a kì yio bá wa ni ìhoho.

4 Nitori awa ti mbẹ ninu agọ́ yi nkerora nitõtọ, ẹrù npa wa: kì iṣe nitori ti awa nfẹ ijẹ alaiwọ̀ṣọ, ṣugbọn ki a le wọ̀ wa li aṣọ, ki iyè ki o le gbé ara kiku mì.

5 Njẹ ẹniti o ṣe wa fun nkan yi ni Ọlọrun, ẹniti o si ti fi akọso Ẹmí fun wa pẹlu.

6 Nitorina awa ni igboiya nigbagbogbo, awa si mọ̀ pe, nigbati awa mbẹ ni ile ninu ara, awa kò si lọdọ Oluwa:

7 (Nitoripe nipa igbagbọ́ li awa nrìn, kì iṣe nipa riri:)

8 Mo ni, awa ni igboiya, awa si nfẹ ki a kuku ti inu ara kuro, ki a si le wà ni ile lọdọ Oluwa.

9 Nitorina awa ndù u, pe bi awa ba wà ni ile tabi bi a kò si, ki awa ki o le jẹ ẹni itẹwọgbà lọdọ rẹ̀.

10 Nitoripe gbogbo wa kò le ṣaima fi ara hàn niwaju itẹ́ idajọ Kristi; ki olukuluku ki o le gbà nkan wọnni ti o ṣe ninu ara, gẹgẹ bi eyi ti o ti ṣe, ibã ṣe rere ibã ṣe buburu.

Iṣẹ́ Ìlàjà

11 Nitorina bi awa ti mọ̀ ẹ̀ru Oluwa, awa nyi enia li ọkàn pada; ṣugbọn a nfi wa hàn fun Ọlọrun; mo si gbagbọ́ pe, a si fi wa hàn li ọkàn nyin pẹlu.

12 Nitori awa kò si ni tún mã yìn ara wa si nyin mọ́, ṣugbọn awa fi àye fun nyin lati mã ṣogo nitori wa, ki ẹ le ni ohun ti ẹ ó fi da wọn lohùn, awọn ti nṣogo lode ara kì isi iṣe li ọkàn.

13 Nitorina bi ori wa ba bajẹ, fun Ọlọrun ni: tabi bi iye wa ba walẹ̀, fun nyin ni.

14 Nitori ifẹ Kristi nrọ̀ wa; nitori awa rò bayi, pe bi ẹnikan ba ti kú fun gbogbo enia, njẹ gbogbo wọn li o ti kú:

15 O si ti kú fun gbogbo wọn, pe ki awọn ti o wà lãye ki o má si ṣe wà lãye fun ara wọn mọ́, bikoṣe fun ẹniti o kú nitori wọn, ti o si ti jinde.

16 Nitorina lati isisiyi lọ awa kò mọ̀ ẹnikan nipa ti ara mọ́; bi awa tilẹ ti mọ̀ Kristi nipa ti ara, ṣugbọn nisisiyi awa kò mọ̀ ọ bẹ̃ mọ́.

17 Nitorina bi ẹnikẹni ba wà ninu Kristi, o di ẹda titun: ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesi i, nwọn si di titun.

18 Ohun gbogbo si ti ọdọ Ọlọrun wá, ẹniti o si ti ipasẹ Jesu Kristi ba wa laja sọdọ ara rẹ̀, ti o si ti fi iṣẹ-iranṣẹ ìlaja fun wa;

19 Eyini ni pe, Ọlọrun wà nínu Kristi, o mba araiye làja sọdọ ara rẹ̀, kò si kà irekọja wọn si wọn lọrùn; o si ti fi ọ̀rọ ìlaja le wa lọwọ.

20 Nitorina awa ni ikọ̀ fun Kristi, bi ẹnipe Ọlọrun nti ọdọ wa ṣipẹ fun nyin: awa mbẹ̀ nyin nipò Kristi, ẹ ba Ọlọrun làja.

21 Nitori o ti fi i ṣe ẹ̀ṣẹ nitori wa, ẹniti kò mọ̀ ẹ̀ṣẹkẹṣẹ rí; ki awa le di ododo Ọlọrun ninu rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13