2. Kor 10 YCE

Paulu Gbèjà Ara Rẹ̀

1 ṢUGBỌN emi Paulu tikarami fi inu tutù ati ìwa pẹlẹ Kristi bẹ̀ nyin, emi ẹni irẹlẹ loju nyin nigbati mo wà larin nyin, ṣugbọn nigbati emi kò si, mo di ẹni igboiya si nyin.

2 Ṣugbọn emi bẹ̀ nyin pe ki o máṣe nigbati mo wà larin nyin ni mo fi igboiya han pẹlu igbẹkẹle ti mo rò pe mo ni igboiya si awọn kan, ti nrò wa si bi ẹniti nrin nipa ti ara.

3 Nitoripe bi awa tilẹ nrìn ni ti ara, ṣugbọn awa kò jagun nipa ti ara:

4 (Nitori ohun ija wa kì iṣe ti ara, ṣugbọn o li agbara ninu Ọlọrun lati wó ibi giga palẹ;)

5 Awa nsọ gbogbo ero kalẹ, ati gbogbo ohun giga ti ngbé ara rẹ̀ ga si ìmọ Ọlọrun, awa si ndi gbogbo ero ni igbekun wá si itẹriba fun Kristi;

6 Awa si ti mura tan lati gbẹsan gbogbo aigbọran, nigbati igbọran nyin ba pé.

7 Ẹnyin si nwò nkan gẹgẹ bi nwọn ti fi ara hàn lode. Bi ẹnikẹni ba gbẹkẹle ara rẹ̀ pe, ti Kristi li on iṣe, ẹ jẹ ki on ki o si tún rò eyi ninu ara rẹ̀ pe, bi on ti jẹ́ ti Kristi, gẹgẹ bẹ̃li awa pẹlu si jẹ́ ti Kristi.

8 Nitori bi mo tilẹ nṣogo aṣerekọja nitori aṣẹ wa, ti Oluwa ti fifun wa fun idagbasoke nyin ki iṣe fun ìbiṣubu nyin, oju ki yio tì mi;

9 Ki o máṣe dabi ẹnipe emi o fi iwe-kikọ dẹruba nyin.

10 Nitori nwọn wipe, iwe rẹ̀ wuwo, nwọn si lagbara; ṣugbọn ìrísi rẹ̀ jẹ alailera, ọ̀rọ rẹ̀ kò nilari.

11 Ki irú enia bẹ̃ ki o ro bayi pe, irú ẹniti awa iṣe li ọ̀rọ nipa iwe-kikọ nigbati awa kò si, irú bẹ̃li awa o si jẹ ni iṣe pẹlu nigbati awa ba wà.

12 Nitoripe awa kò daṣa ati kà ara wa mọ́, tabi ati fi ara wa wé awọn miran ninu wọn ti ńyìn ara wọn; ṣugbọn awọn tikarawọn jẹ alailoye nigbati nwọn nfi ara wọn diwọn ara wọn, ti nwọn si nfi ara wọn wé ara wọn.

13 Ṣugbọn awa kò ṣogo rekọja ãlà wa, ṣugbọn nipa ãlà ti Ọlọrun ti pín fun wa, ani ãlà kan lati de ọdọ nyin.

14 Nitori awa kò nawọ́ wa rekọja rara, bi ẹnipe awa kò de ọdọ nyin: nitori awa tilẹ de ọdọ nyin pẹlu ninu ihinrere Kristi.

15 Awa kò ṣogo rekọja ãlà wa, eyini ni lori iṣẹ ẹlomiran; ṣugbọn awa ni ireti pe, bi igbagbọ nyin ti ndagba si i, gẹgẹ bi àla wa awa o di gbigbega lọdọ nyin si i lọpọlọpọ,

16 Ki a ba le wasu ihinrere ani ni ẹkùn ti mbẹ niwaju nyin, ki a má si ṣogo ninu ãlà ẹlomiran nipa ohun ti o wà li arọwọto.

17 Ṣugbọn ẹniti o ba nṣogo, ki o mã ṣogo ninu Oluwa.

18 Nitoripe kì iṣe ẹniti nyìn ara rẹ̀ li o yanju, bikoṣe ẹniti Oluwa yìn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13