2. Kor 8 YCE

Àwọn Onigbagbọ Ará Masedonia Lawọ́

1 PẸLUPẸLU, ará, awa nsọ fun nyin niti ore-ọfẹ Ọlọrun, ti a fifun awọn ijọ Makedonia;

2 Bi o ti jẹ pe ninu ọpọ idanwò ipọnju, ọ̀pọlọpọ ayọ̀ wọn ati ibu aini wọn di pipọ si ọrọ̀ ilawọ wọn,

3 Nitori mo jẹri pe gẹgẹ bi agbara wọn, ani ju agbara wọn, nwọn ṣe e lati ifẹ inu ara wọn,

4 Nwọn nfi ẹ̀bẹ pipọ rọ̀ wa niti ẹbun ọfẹ yi, ati ti idapọ ninu iṣẹ-iranṣẹ fun awọn enia mimọ́:

5 Ati eyi, ki iṣe bi awa ti rò rí, ṣugbọn nwọn tètekọ fi awọn tikarawọn fun Oluwa, ati fun wa, nipa ifẹ Ọlọrun;

6 Tobẹ̃ ti awa fi gba Titu niyanju pe, bi o ti bẹ̀rẹ na, bẹ̃ni ki o si pari ẹbun ọfẹ yi ninu nyin pẹlu.

7 Ṣugbọn bi ẹnyin ti pọ̀ li ohun gbogbo, ni igbagbọ́, ati ọ̀rọ, ati ìmọ, ati ninu igbiyanjú gbogbo, ati ni ifẹ nyin si wa, ẹ kiyesi ki ẹnyin ki o pọ̀ ninu ẹbun ọfẹ yi pẹlu.

8 Kì iṣe nipa aṣẹ ni mo fi nsọ, ṣugbọn ki a le ri idi otitọ ifẹ nyin pẹlu, nipa igbiyanjú awọn ẹlomiran.

9 Nitori ẹnyin mọ̀ ore-ọfẹ Oluwa wa Jesu Kristi, pe bi on ti jẹ ọlọrọ̀ rí, ṣugbọn nitori nyin o di talaka, ki a le sọ nyin di ọlọrọ̀ nipa aini rẹ̀.

10 Ati ninu eyi ni mo fi imọran mi fun nyin: nitori eyi ṣanfani fun nyin, ẹnyin ti o kọ́ bẹrẹ niwọn ọdún ti o kọja, kì iṣe lati ṣe nikan, ṣugbọn lati fẹ́ pẹlu.

11 Njẹ nisisiyi ẹ pari ṣiṣe na pẹlu; bi imura-tẹlẹ ati ṣe ti wa, bẹni ki ipari si wa lati inu agbara nyin:

12 Nitori bi imura-tẹlẹ ba wà ṣaju, o jasi itẹwọgbà gẹgẹ bi ohun ti enia bá ni, kì iṣe gẹgẹ bi ohun ti kò ni.

13 Nitori emi kò fẹ ki awọn ẹlomiran wà ni irọrun, ki o si jẹ ipọnju fun nyin,

14 Ṣugbọn nipa idọgba, pe ki ọpọlọpọ ini nyin li akoko yi le ṣe ẹkún aini wọn, ki ọ̀pọlọpọ ini wọn pẹlu le ṣe ẹkún aini nyin: ki idọgba ki o le wà:

15 Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ẹniti o kó pọ̀ju, kò ni nkan le; ẹniti o si kó kere ju, kò ṣe alainito.

Titu ati Àwọn Ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀

16 Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun, ẹniti o fi itara aniyan kanna yi si ọkàn Titu fun nyin.

17 Nitori on gbà ọ̀rọ iyanju nitõtọ; ṣugbọn bi o ti ni itara pipọ, on tikararẹ̀ tọ̀ nyin wá fun ara rẹ̀.

18 Awa ti rán arakunrin na pẹlu rẹ̀, iyìn ẹniti o wà ninu ihinrere yiká gbogbo ijọ.

19 Kì si iṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn ẹniti a ti yàn pẹlu lati ọdọ ijọ wá lati mã bá wa rìn kiri ninu ọran ore-ọfẹ yi, ti awa nṣe iranṣẹ rẹ̀ fun ogo Oluwa, ati imura-tẹlẹ wa.

20 Awa nyẹra fun eyi, ki ẹnikẹni má bã ri wi si wa nitori ọ̀pọ yi ti awa pin.

21 Awa ngbero ohun rere, kì iṣe niwaju Oluwa nikan, ṣugbọn niwaju enia pẹlu.

22 Awa si ti rán arakunrin wa pẹlu wọn, ẹniti awa ri daju nigba pipọ pe o ni itara ninu ohun pipọ, ṣugbọn nisisiyi ni itara rẹ̀ tubọ pọ si i nipa igbẹkẹle nla ti o ni si nyin.

23 Bi ẹnikẹni ba mbère ẹniti Titu iṣe, ẹlẹgbẹ ati olubaṣiṣẹ mi ni nitori nyin: tabi awọn arakunrin wa li ẹnikẹni mbère ni, iranṣẹ ijọ ni nwọn iṣe, ati ogo Kristi.

24 Nitorina ẹ fi ẹri ifẹ nyin hàn wọn niwaju ijọ, ati iṣogo wa nitori nyin.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13