2. Kor 6 YCE

1 NJẸ bi alabaṣiṣẹpọ pẹlu rẹ̀, awa mbẹ̀ nyin ki ẹ máṣe gbà ore-ọfẹ Ọlọrun lasan.

2 (Nitori o wipe, emi ti gbohùn rẹ li akokò itẹwọgbà, ati li ọjọ igbala ni mo si ti ràn ọ lọwọ: kiyesi i, nisisiyi ni akokò itẹwọgbà; kiyesi i, nisisiyi ni ọjọ igbala.)

3 A kò si ṣe ohun ikọsẹ li ohunkohun, ki iṣẹ-iranṣẹ ki o máṣe di isọrọ buburu si.

4 Ṣugbọn li ohun gbogbo awa nfi ara wa han bi awọn iranṣẹ Ọlọrun ninu ọ̀pọlọpọ sũru, ninu ipọnju, ninu aini, ninu wahalà,

5 Nipa ìnà, ninu tubu, nipa ìrúkerudo, nipa ìṣẹ́, ninu iṣọra, ninu igbawẹ;

6 Nipa ìwa mimọ́, nipa ìmọ, nipa ipamọra, nipa iṣeun, nipa Ẹmi Mimọ́, nipa ifẹ aiṣẹtan,

7 Nipa ọ̀rọ otitọ, nipa agbara Ọlọrun, nipa ihamọra ododo li apa ọtún ati li apa òsi,

8 Nipa ọlá ati ẹ̀gan, nipa ìhin buburu ati ìhin rere: bi ẹlẹtan, ṣugbọn a jasi olõtọ;

9 Bi ẹniti a kò mọ̀, ṣugbọn a mọ̀ wa dajudaju; bi ẹniti nkú lọ, si kiyesi i, awa wà lãye; bi ẹniti a ńnà, a kò si pa wa;

10 Bi ẹniti o kún fun ibinujẹ, ṣugbọn awa nyọ̀ nigbagbogbo; bi talakà, ṣugbọn awa nsọ ọ̀pọlọpọ di ọlọrọ̀; bi ẹniti kò ni nkan, ṣugbọn awa ni ohun gbogbo.

11 Ẹnyin ara Korinti, a ti bá nyin sọ otitọ ọ̀rọ, ọkàn wa ṣipayá sí nyin.

12 A kò ni nyin lara nitori wa, ṣugbọn a ńni nyin lara nitori ifẹ-ọkàn ẹnyin tikaranyin.

13 Njẹ fun ẹsan iru kanna (emi nsọ bi ẹnipe fun awọn ọmọ mi,) ki ẹnyin di kikún pẹlu.

Ilé Ọlọrun Alààyè

14 Ẹ máṣe fi aidọgba dàpọ pẹlu awọn alaigbagbọ́: nitori ìdapọ kili ododo ni pẹlu aiṣododo? ìdapọ kini imọlẹ si ni pẹlu òkunkun?

15 Irẹpọ̀ kini Kristi si ni pẹlu Beliali? tabi ipin wo li ẹniti o gbagbọ́ ni pẹlu alaigbàgbọ?

16 Irẹpọ̀ kini tẹmpili Ọlọrun si ni pẹlu oriṣa? nitori ẹnyin ni tẹmpili Ọlọrun alãye; gẹgẹ bi Ọlọrun ti wipe, Emi ó gbé inu wọn, emi o si mã rìn ninu wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nwọn o si jẹ enia mi.

17 Nitorina ẹ jade kuro larin wọn, ki ẹ si yà ara nyin si ọ̀tọ, li Oluwa wi, ki ẹ máṣe fi ọwọ́ kàn ohun aimọ́; emi o si gbà nyin.

18 Emi o si jẹ Baba fun nyin, ẹnyin o si jẹ ọmọkunrin mi ati ọmọbinrin mi, li Oluwa Olodumare wi.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13