10 Nitorina emi ni inu didùn ninu ailera gbogbo, ninu ẹ̀gan gbogbo, ninu aini gbogbo, ninu inunibini gbogbo, ninu wahalà gbogbo nitori Kristi: nitori nigbati mo ba jẹ alailera, nigbana ni mo di alagbara.
11 Mo di wère nipa ṣiṣogo; ẹnyin li o mu mi ṣe e: nitoriti o tọ́ ti ẹ ba yìn mi: nitoriti emi kò rẹ̀hin li ohunkohun si awọn Aposteli gigagiga na, bi emi kò tilẹ jamọ nkankan.
12 Nitõtọ a ti ṣe iṣẹ àmi Aposteli larin nyin ninu sũru gbogbo, ninu iṣẹ àmi, ati iṣẹ iyanu, ati iṣẹ agbara.
13 Nitori ninu kili ohun ti ẹnyin rẹ̀hin si ijọ miran, bikoṣe niti pe emi tikarami ko jẹ oniyọnu fun nyin? ẹ dari aṣiṣe yi ji mi.
14 Kiyesi i, igba kẹta yi ni mo mura tan lati tọ̀ nyin wá; emi kì yio si jẹ oniyọnu fun nyin: nitoriti emi kò wá nkan nyin, bikoṣe ẹnyin tikaranyin: nitoriti kò tọ́ fun awọn ọmọ lati mã tò iṣura jọ fun awọn õbi wọn, bikoṣe awọn õbi fun awọn ọmọ wọn.
15 Emi ó si fi ayọ̀ náwo, emi ó si ná ara mi fun ọkàn nyin nitõtọ; bi mo tilẹ fẹ nyin lọpọlọpọ, diẹ li a ha fẹran mi?
16 Ṣugbọn o dara bẹ̃, ti emi kò dẹruba nyin: ṣugbọn bi ọlọgbọn, emi nfi ẹ̀rọ mu nyin.