4 Bi a ti gbé e lọ soke si Paradise, ti o si gbọ́ ọ̀rọ ti a kò le sọ, ti kò tọ́ fun enia lati mã sọ.
5 Nipa irú ẹni bẹ̃ li emi ó ma ṣogo: ṣugbọn nipa ti emi tikarami emi kì yio ṣogo, bikoṣe ninu ailera mi.
6 Nitoripe bi emi tilẹ nfẹ mã ṣogo, emi kì yio jẹ aṣiwère; nitoripe emi ó sọ otitọ: ṣugbọn mo kọ̀, ki ẹnikẹni ki o má bã fi mi pè jù ohun ti o ri ti emi jẹ lọ, tabi ju eyiti o gbọ lẹnu mi.
7 Ati nitori ọ̀pọlọpọ iṣipaya, ki emi ki o má ba gbé ara mi ga rekọja, a si ti fi ẹgún kan si mi lara, iranṣẹ Satani, lati pọn mi loju, ki emi ki o má ba gberaga rekọja.
8 Nitori nkan yi ni mo ṣe bẹ̀ Oluwa nigba mẹta pe, ki o le kuro lara mi.
9 On si wi fun mi pe, Ore-ọfẹ mi to fun ọ: nitoripe a sọ agbara mi di pipé ninu ailera. Nitorina tayọ̀tayọ̀ li emi ó kuku ma ṣogo ninu ailera mi, ki agbara Kristi ki o le mã gbe inu mi.
10 Nitorina emi ni inu didùn ninu ailera gbogbo, ninu ẹ̀gan gbogbo, ninu aini gbogbo, ninu inunibini gbogbo, ninu wahalà gbogbo nitori Kristi: nitori nigbati mo ba jẹ alailera, nigbana ni mo di alagbara.