7 Ati nitori ọ̀pọlọpọ iṣipaya, ki emi ki o má ba gbé ara mi ga rekọja, a si ti fi ẹgún kan si mi lara, iranṣẹ Satani, lati pọn mi loju, ki emi ki o má ba gberaga rekọja.
8 Nitori nkan yi ni mo ṣe bẹ̀ Oluwa nigba mẹta pe, ki o le kuro lara mi.
9 On si wi fun mi pe, Ore-ọfẹ mi to fun ọ: nitoripe a sọ agbara mi di pipé ninu ailera. Nitorina tayọ̀tayọ̀ li emi ó kuku ma ṣogo ninu ailera mi, ki agbara Kristi ki o le mã gbe inu mi.
10 Nitorina emi ni inu didùn ninu ailera gbogbo, ninu ẹ̀gan gbogbo, ninu aini gbogbo, ninu inunibini gbogbo, ninu wahalà gbogbo nitori Kristi: nitori nigbati mo ba jẹ alailera, nigbana ni mo di alagbara.
11 Mo di wère nipa ṣiṣogo; ẹnyin li o mu mi ṣe e: nitoriti o tọ́ ti ẹ ba yìn mi: nitoriti emi kò rẹ̀hin li ohunkohun si awọn Aposteli gigagiga na, bi emi kò tilẹ jamọ nkankan.
12 Nitõtọ a ti ṣe iṣẹ àmi Aposteli larin nyin ninu sũru gbogbo, ninu iṣẹ àmi, ati iṣẹ iyanu, ati iṣẹ agbara.
13 Nitori ninu kili ohun ti ẹnyin rẹ̀hin si ijọ miran, bikoṣe niti pe emi tikarami ko jẹ oniyọnu fun nyin? ẹ dari aṣiṣe yi ji mi.