2 Mo ti sọ fun nyin ṣaju, mo si nsọ fun nyin tẹlẹ, bi ẹnipe mo wà pẹlu nyin nigba keji, ati bi emi kò ti si lọdọ nyin nisisiyi, mo kọwe si awọn ti o ti ṣẹ̀ na, ati si gbogbo awọn ẹlomiran, pe bi mo ba tún pada wá, emi kì yio da wọn si:
3 Niwọnbi ẹnyin ti nwá àmi Kristi ti nsọ̀rọ ninu mi, ẹniti ki iṣe ailera si nyin, ṣugbọn ti o jẹ agbara ninu nyin.
4 Nitoripe a kàn a mọ agbelebu nipa ailera, ṣugbọn on wà lãye nipa agbara Ọlọrun. Nitori awa pẹlu jasi alailera ninu rẹ̀, ṣugbọn awa ó wà lãye pẹlu rẹ̀ nipa agbara Ọlọrun si nyin.
5 Ẹ mã wadi ara nyin, bi ẹnyin bá wà ninu igbagbọ́; ẹ mã dan ara nyin wò. Tabi ẹnyin tikaranyin kò mọ̀ ara nyin pe Jesu Kristi wà ninu nyin? afi bi ẹnyin ba jẹ awọn ti a tanù.
6 Ṣugbọn mo ni igbẹkẹle pe ẹnyin ó mọ̀ pe, awa kì iṣe awọn ti a tanù.
7 Njẹ awa ngbadura si Ọlọrun, ki ẹnyin ki o máṣe ibikibi kan; kì iṣe nitori ki awa ki o le fi ara hàn bi awọn ti a mọ̀ daju, ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mã ṣe eyi ti o dara, bi awa tilẹ dabi awọn ti a tanù.
8 Nitori awa kò le ṣe ohun kan lodi si otitọ, bikoṣe fun otitọ.