6 Ṣugbọn mo ni igbẹkẹle pe ẹnyin ó mọ̀ pe, awa kì iṣe awọn ti a tanù.
7 Njẹ awa ngbadura si Ọlọrun, ki ẹnyin ki o máṣe ibikibi kan; kì iṣe nitori ki awa ki o le fi ara hàn bi awọn ti a mọ̀ daju, ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mã ṣe eyi ti o dara, bi awa tilẹ dabi awọn ti a tanù.
8 Nitori awa kò le ṣe ohun kan lodi si otitọ, bikoṣe fun otitọ.
9 Nitori awa nyọ̀, nigbati awa jẹ alailera, ti ẹnyin si jẹ alagbara: eyi li awa si ngbadura fun pẹlu, ani pipe nyin.
10 Nitori idi eyi, nigbati emi kò si, mo kọwe nkan wọnyi pe, nigbati mo ba de, ki emi ki o má bã lò ikannú, gẹgẹ bi aṣẹ ti Oluwa ti fifun mi fun idagbasoke, kì si iṣe fun iparun.
11 Li akotan, ará, odigboṣe. Ẹ jẹ pipé, ẹ tújuka, ẹ jẹ oninu kan, ẹ mã wà li alafia; Ọlọrun ifẹ ati ti alafia yio wà pẹlu nyin.
12 Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ kí ara nyin.