3 Emi si kọwe nitori eyi kanna si nyin pe, nigbati mo ba si de, ki emi ki o máṣe ni ibinujẹ lọdọ wọn, nitori awọn ti emi iba mã yọ̀: nitoriti mo ni igbẹkẹle ninu gbogbo nyin, nitori ayọ̀ mi li ayọ̀ fun gbogbo nyin.
4 Nitoripe ninu ọ̀pọlọpọ wahalà ati arodun ọkan mi ni mo ti fi ọ̀pọlọpọ omije kọwe si nyin; kì iṣe nitori ki a le bà nyin ninu jẹ, ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mọ̀ ifẹ ti mo ni si nyin lọpọlọpọ rekọja.
5 Ṣugbọn bi ẹnikẹni ba ti mu ibinujẹ wá, on kò bà mi ni inu jẹ, bikoṣe niwọn diẹ: ki emi ki o máṣe di ẹru l'ẹ̀ru gbogbo nyin.
6 Ìya yi ti ọpọlọpọ ti fi jẹ iru enia bẹ̃, o to fun u.
7 Kaka bẹ ẹ, ẹnyin iba kuku darijì i, ki ẹ si tù u ninu, lọnakọna ki ọpọlọpọ ibanujẹ má bã bò iru enia bẹ̃ mọlẹ.
8 Nitorina mo bẹ̀ nyin, ẹ fi ifẹ nyin han daju si oluwarẹ̀.
9 Nitori eyi na pẹlu ni mo ti kọwe, ki emi ki o le mọ̀ ẹri nyin, bi ẹnyin ba ṣe eletí ọmọ li ohun gbogbo.