3 Bi a ti fi nyin hàn pe, iwe Kristi ni nyin, ti a nṣe iranṣẹ fun, kì iṣe eyiti a fi tadawa kọ, bikoṣe Ẹmí Ọlọrun alãye; kì iṣe ninu tabili okuta, bikoṣe ninu tabili ọkàn ẹran.
4 Irú igbẹkẹle yi li awa si ni nipa Kristi sọdọ Ọlọrun:
5 Kì iṣe pe awa to fun ara wa lati ṣirò ohunkohun bi ẹnipe lati ọdọ awa tikarawa; ṣugbọn lati ọdọ Ọlọrun ni tito wa;
6 Ẹniti o mu wa tó bi iranṣẹ majẹmu titun; kì iṣe ti iwe, bikoṣe ti ẹmí: nitori iwe a mã pani, ṣugbọn ẹmí a mã sọni di ãye.
7 Ṣugbọn bi iṣẹ-iranṣẹ ti ikú, ti a ti kọ ti a si ti gbẹ́ si ara okuta, ba jẹ ologo, tobẹ̃ ti awọn ọmọ Israeli kò le tẹjumọ ati wò oju Mose, nitori ogo oju rẹ̀ (ogo nkọja lọ),
8 Yio ha ti ri ti iṣẹ-iranṣẹ ti ẹmí kì yio kuku jẹ ogo jù?
9 Nitoripe bi iṣẹ-iranṣẹ idalẹbi ba jẹ ologo, melomelo ni iṣẹ-iranṣẹ ododo yio rekọja li ogo.