8 A npọn wa loju niha gbogbo, ṣugbọn ara kò ní wa: a ndãmú wa, ṣugbọn a kò sọ ireti nù.
9 A nṣe inunibini si wa, ṣugbọn a kò kọ̀ wa silẹ; a nrẹ̀ wa silẹ, ṣugbọn a kò si pa wa run;
10 Nigbagbogbo awa nru ikú Jesu Oluwa kiri li ara wa, ki a le fi ìye Jesu hàn pẹlu li ara wa.
11 Nitoripe nigbagbogbo li a nfi awa ti o wà lãyè fun ikú nitori Jesu, ki a le fi ìye Jesu hàn ninu ara kikú wa pẹlu.
12 Bẹ̃ni ikú nṣiṣẹ ninu wa, ṣugbọn ìye ninu nyin.
13 Awa li ẹmí igbagbọ́ kanna, gẹgẹ bi a ti kọ́ ọ pe, emi gbagbọ́, nitorina li emi ṣe sọ: awa pẹlu gbagbọ́, nitorina li awa si ṣe nsọ;
14 Awa mọ̀ pe, ẹniti o jí Jesu Oluwa dide yio si jí wa dide pẹlu nipa Jesu, yio si mu wa wá iwaju rẹ̀ pẹlu nyin.